Awọn ọdọ dana sun eeyan meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn l’Ọja-Ọdan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Idajọ oju-ẹsẹ lawọn ọdọ kan ti wọn le lọgọrun-un ṣe fawọn ọkunrin meji ti wọn ba ori eeyan tutu lọwọ wọn lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila oṣu Keji, ọdun 2022 yii, ni Ọja-Ọdan, Yewa, nipinlẹ Ogun. Niṣe ni wọn wọ wọn jade nibi tawọn oọlọpaa fi wọn si, wọn si dana sun wọn di eeru ti ẹnikẹni ko le da wọn mọ mọ.

Ìdòwú Afọlábí ati Johnson Adebiyi lorukọ awọn ọkunrin meji to n gbe ori eeyan tutu kiri naa. Ori naa kì í ṣe ẹyọ kan bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.

Nigba tọwọ ba wọn, awọn ọlọpaa ko wọn satimọle, ṣugbọn awọn ọdọ tinu n bi nitori eyi, ya bo teṣan ọlọpaa Ọja-Ọdan ti wọn fi awọn afurasi ọdaran naa si, won fipa wọ wọn jade lọdọ awọn ọlọpaa, ni wọn ba ju taya si Idowu ati Johnson lọrun, wọn dana sun wọn raurau niwaju teṣan naa.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ lo waye bẹẹ, ati pe kọmandi ọlọpaa yoo fi atẹjade sita lori rẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, nigba toun ba ti ni ẹkunrẹrẹ alaye lori ẹ.

Ẹ oo ranti pe ọjọ Abamẹta, Satide yii kan naa tọwọ ba awọn meji l’Ọja-Ọdán yii naa ni awọn ọlọpaa mu tọkọ-tiyawo kan pẹlu ẹya ara eeyan loriṣiiriṣii ni Lẹmẹ, l’Abẹokuta, bẹẹ ni ti Sọfia tawọn ọmọdekunrin kan ge lori lọsẹ meji sẹyin ṣẹṣẹ de kootu l’Abẹokuta kan naa.

Awọn iṣẹlẹ aburu to n ṣẹlẹ leralera, to si fẹẹ sọ ipinlẹ Ogun lẹnu yii lo fa a tawọn ọdọ to dana sun eeyan meji yii ṣe tete ṣe bẹẹgẹgẹ bawọn eeyan ṣe wi. Wọn ni wọn ko fẹ kawọn afeeyan ṣowo yii maa pọ si i ni.

Leave a Reply