Awọn ọdọ gba teṣan ọlọpaa n’Ibadan lọwọ awọn ọmọọta, wọn ko jẹ ki wọn dana sun un

Aderounmu Kazeem

Ọdọmọkunrin kan ni aṣita ibọn ọlọpaa ti pa danu bayii niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lasiko tawọn janduku kan fẹẹ jo teṣan ọlọpaa to wa ni Mọkọla.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe awọn ọdọ adugbo naa ni wọn ko gba awọn jadnuku ọhun laye nigba ti wọn kọlu teṣan ọlọpaa naa pẹlu awọn ohun ija oloro lọwọ, ti wọn si fẹẹ sọ ina si i.

Wọn ni nibi tawọn janduku to fẹẹ jo teṣan yii ti n dunkooko lati sọ ina si teṣan Mọkọla yii, nibẹ gan-an ni aṣita ibọn ti ba eeyan kan, to si ku ki o too ri iranwọ kankan.

Lara ohun ti wọn sọ pe awọn janduku ọhun fẹẹ ji ko ni aṣọ awọn ọlọpaa, ṣugbọn ti awọn ọdọ agbegbe naa fariga mọ wọn lọwọ, ti wọn ko jẹ ki wọn ri ohunkohun ṣe.

Bi wọn ti ṣe n du ki wọn ma ri teṣan ọlọpaa ọhun jo, bẹẹ ni oriṣiiriṣi akitiyan naa tun waye lati daabo bo ile iwosan UCH, ki wọn ma baa sọ ina si i pẹlu.

Ninu ọrọ agbẹnusọ fun ileẹṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi lo ti sọ ọ lori redio kan n’Ibadan pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, ati pe alaafia ti pada si agbegbe naa.

Bakan naa lo fi kun un pe gbogbo ipa lawọn n sa bayii ki awọn janduku naa ma le ri ọsibitu UCH jo atawọn dukia mi-in to jẹ tijoba kaakiri ipinlẹ naa.

 

Leave a Reply