Awọn ọdọ kan fẹẹ ra fọọmu lati dupo aarẹ fun Tinubu

Jọkẹ Amọri

Lati mu ki erongba Aṣiwaju Bọla Tinubu lati di aarẹ Naijiria wa si imuṣẹ, awọn ọdọ kan ti wọn pera wọn ni Nigerian Youths for Tinubu ti kora wọn jọ, ti wọn si ti fifẹ han lati ra fọọmu idije sipo aarẹ fun gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa.

Idiris Arẹgbeẹ ti i ṣe oludari awọn ẹgbẹ yii sọrọ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ọkunrin naa ni ohun to fa igbesẹ tawọn fẹẹ gbe yii ko ju pe Aṣiwaju kun oju oṣuwọn fun ipo yii, bẹẹ ni yoo tẹ ifẹ awọn araalu lọrun to ba de ipo naa. O fi kun un pe ọkunrin oloṣelu naa jẹ eeyan kan to ni iran, o jẹ ẹni kan to gbagbọ ninu ijọba onitẹsiwaju, o jẹ ẹni to ni afojusun, ti ki i si i kuro nidii rẹ titi ti yoo fi ṣe aṣeyọri lori afojusun rẹ.

Idris ni Naijiria nilo ẹni to ṣee fọkan tan, to si ṣee gbẹkẹle, to mọ ibi ti bata ti n ta awọn araalu lẹsẹ, to si ni agbara lati mu atunṣe wa fun wọn.

O ni oun ko ro pe ẹlomi-in tun wa to kun oju oṣuwọn bii Tinubu, idi niyi ti awọn fi wa lẹyin rẹ, ti awọn si ṣetan lati gba fọọmu lati dupo aarẹ fun un, pẹlu idaniloju pe yoo bori to ba dije, eyi lo fa ipinnu awọn lati ra fọọmu fun un.

Leave a Reply