Awọn ọdọ kan kọju ija sawọn to n ṣe iwọde ‘Yoruba Nation’ niluu Ọffa

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọṣẹ yii, lawọn ọdọ kan kora jọ si agbegbe Sẹkiteriati ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu Ọffa, ODU, niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara, lati ṣe iwọde idasilẹ orileede Yoruba, ṣugbọn to pada fori sanpọn.

ALAROYE gbọ pe awọn to n pe fun idasilẹ orileede Yoruba, ‘Yoruba Nation, kora jọ, pẹlu ero ati maa wọde kaakiri ilu, ti awọn ẹṣọ alaabo si wa pẹlu wọn, ki rogbodiyan ma baa waye.

A gbọ pe ni kete ti iwọde naa bẹrẹ lawọn ọdọ kan lọọ di wọn lọwọ pe wọn o gbọdọ ṣe iwọde kankan niluu Ọffa, eyi lo sokunfa bi awọn ọlọpaa ṣe da iwọde naa duro.

Nigba ti ALAROYE pe Ọlọfa ti iluu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamosi Ajagungbade, Esuwoye keji, lati gbọ iroyin lori iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ kabiyesi ni awọn naa n gbọ iroyin yii ni, ṣugbọn iwaju aafin lawọn wa bayii, awọn ko ri awọn to n ṣe iwọde kankan, bẹẹ lawọn ọlọpaa ti duro wamuwamu si iwaju aafin bayii.

Leave a Reply