Awọn ọdọ kan lọọ ṣa alaga ẹgbẹ CAN pa mọle ni Kano

Faith Adebọla

Ọpọ eeyan lo ti n bẹnu atẹ lu iku gbigbona tawọn ọdọ kan tinu n bi fi pa Alaga ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹni, Christian Association of Nigeria (CAN), Pasitọ Shaibu, ti wọn ṣa pa mọ ile rẹ nipinlẹ Kano.

Ba a ṣe gbọ, ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa waye labule Masu, niluu Kano, nipinlẹ Kano kan naa. Pasitọ yii ni Alaga ẹgbẹ CAN, ẹka ti ijọba ibilẹ Sumaila, nipinlẹ Kano.

Ko ti i sẹni to le sọ pato ohun to fa akọlu ati itajẹsilẹ yii.

Ọkunrin kan, Ọgbẹni Bismark, to sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sori ikanni ayelujara rẹ sọ pe lati ọsẹ diẹ lawọn ẹlẹsin Musulumi to wa lagbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye ti n koro oju si bi ẹsin Kristẹni ṣe n gberu nijọba ibilẹ ati adugbo toloogbe naa wa, wọn ni akitiyan oloogbe yii ko tẹ wọn lọrun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iku oro yii, ki wọn si mọ awọn to wa lẹyin iṣẹlẹ ọhun, ki wọn le fi wọn jofin.

Ọpọ araalu to sọrọ lori iṣẹlẹ buruku yii lo kilọ pe iwa aidaa lawọn to ṣe akọlu naa hu, ati pe iru iṣẹlẹ yii le fa ogun ẹsin tijọba ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ.

Leave a Reply