Awọ̣n ọdọ Naijria yoo tun jade ṣewọde lẹẹkan si i

Aderounmu Kazeem

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba,  Ahmad Lawan, ti sọ pe awọn ọdọ orilẹ-ede yii yoo tun ya jade lẹẹkan si i, lati fẹhonu han, bẹẹ ni yoo lagbara ju tatẹyinwa lo, ti ipese iṣẹ lọpọ yanturu ko ba tete bẹrẹ bayii.

Ana Monde, ọjọ Aje, lasiko ti minisita fun iṣẹ ọgbin ati idagbasoke igberiko wa siwaju awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati ṣe atotonu lori bo ṣe fẹẹ nawo ninu eto iṣuna owo lọdun 2021, ni olori ile igbimọ aṣofin agba yii pe akiyesi ọhun.

O ni o ṣe pataki ki ijọba, awọn aṣofin atawọn mi-in ti ọrọ kan gbiyanju lati pese iṣẹ lọpọ yanturu fun awọn ọdọ, nitori iṣẹ ọfiisi ati iṣẹ epo ko fẹẹ ka awọn eeyan orilẹ-ede yii mọ, paapaa awọn ọdọ to nilo iṣẹ.

Bakan naa lo fi kun un pe eto iṣuna owo fọdun 2021 ti kaluku wa n ṣe atotonu lori bi yoo ti ṣe na an yii loju awọn aṣofin gbọdọ ni eto ipese iṣẹ f’awọn ọdọ ninu, ki iwọde mi-in ma tun bẹ silẹ laipẹ ọjọ.

Lawan sọ pe, iwọde tawọn ọdọ ṣe kọja yii, gbogbo aye pata lo gbọ ohun wọn, ti wọn si ri i pe ootọ pọnbele loun ti wọn n beere fun, bo tilẹ jẹ pe awọn janduku alainikanṣe kan fi iwa aitọ da iwọde ọhun ru nigbẹyin.

O ni, asiko niyi lati tete pese silẹ fun wọn, ki wọn ma tun lọ jade lẹẹkan si i.

 

2 thoughts on “Awọ̣n ọdọ Naijria yoo tun jade ṣewọde lẹẹkan si i

  1. Ero mi ni wipe kii ise nikan lole mu ki odo Jade lekan sii, bikose wipe ki ounje po yauturu, owo ti osise ngba koto lati ra gbogbo nkan mo, ati gbogbo ehonu awon odo ki won ri wipe won mu se, bibeko

  2. Ki won pese ise kiwonmonje ki awon olopa kositom kai lasimon eso ojuonon gbowo lowo aralumon enitobatise sofin kolosanwo si bank ijoba tiabalesebe aripe iluyiodara

Leave a Reply