Awọn ọdọ Ọjagbọọrọ ni Kwara pariwo: Gomina gba wa o, gbogbo ileewe ilu wa lo ti d’alapa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ẹgbẹ idagbasoke ọdọ agbegbe Ọjagbọọrọ, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ilọrin (East), nipinlẹ Kwara, ti kegbanjare si Gomina Abdurahman Abdulrazaq Olori awọn aṣofin, Ọnarebu Yakubu Danladi, lati waa tun ileewe agbegbe naa ṣe latari bi gbogbo ẹ ṣe di ẹbiti alapa bayii.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ ọhun gbe jade to tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti rọ ijọba Kwara lati tete wa wọrọkọ fi sada lori ibeere awọn, wọn ni eto ẹkọ ṣe koko, bẹẹ lo ṣe pataki, to si yẹ kijọba mu un ni ọkunkundun. Wọn ni ẹkọ ni ọjọ ọla awọn ogo wẹẹrẹ.

Wọn ni Ọnarebu to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ Oorun Ilọrin (East), Ali Amuda Jimoh, ti fẹẹ ba iṣẹ rere gomina jẹ, to si fẹẹ ba ọjọ ọla eto ẹkọ awọn ogo wẹẹrẹ jẹ pẹlu bo ṣe gbe anfaani ti aduugbo naa ni si eto ẹkọ ta kete si wọn.

Wọn tun fi kun un pe Ọnarebu Jimoh ṣeleri lati tun orule yara ikẹkọọ meji ṣe fun awọn akẹkọọ, ṣugbọn ti ko ṣe nnkan kan lori ileewe ọhun titi di bi a ṣe n sọ yii.

Awọn ọdọ ọhun ti waa ni, oriṣa bo o le gbe mi, ṣe mi bo o ṣe ba mi, wọn rọ Ọnarebu Amuda Jimoh ko da awọn orule ti wọn ṣi pada, nigba ti agbara rẹ ko ka a mọ, awọn yoo si gbinyaju lati tun yara ikẹkọọ naa kọ funra awọn ti ijọba ba kọ lati ran awọn lọwọ.

 

Leave a Reply