Awọn ọdọ pariwo ole le Pasuma lori nibi ti wọn ti n ṣewọde ta ko SARS l’Ekoo

Jide Alabi

Latijọ ti gbajumọ olorin fújì yii ti di ilu-mọ-ọn-ka nídìí iṣẹ ẹ, itiju nla tawọn ọdọ ṣe fun un ni Alausa, Ikẹja, l’Ekoo, ṣee ṣe kiru ẹ ma ṣẹlẹ si i ri, nitori bi wọn ṣe n pe e lole, ni wọn n ho le e gidigidi, tawọn ololufẹ ẹ sí sare gbe e kuro laarin wọn ki wọn too ṣe e lese.
Gbajumọ olorin fújì nní, Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, lawọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde ta ko ẹṣọ agbofinro SARS atawọn iwa buruku mi-in tawọn agbofinro naa n hu kọlu, nigba to lọ saarin wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Wọn ni bi ọkunrin olorin yii ṣe debẹ, to ni ki wọn fun oun ni ẹrọ amohun-dun-gbẹmu ni ariwo buruku sọ laarin ero, tawon kan si n pariwo ‘no… no… no..’ eyi to tumọ si, “Rara o, a ko fẹẹ gbọ ohun rẹ nibi rara)

Wọn ni bi wọn ṣe n pariwo niyi, ki ọrọ ọhun si too di wahala ti apa ọkunrin olorin yii ko ni i ka lo fi tete kuro laarin awọn ọdọ ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju asiko yii lawọn ọdọ to n ṣewọde yii ti n sọ pe pupọ ninu awọn olorin lawọn ti ri ti wọn waa fara han pe awọn naa jọ n ṣe e ni, ṣugbọn tawọn ko ri Wasiu Alabi Pasuma rara.

Bi Alabi naa ṣe gbọ ọrọ yii loun paapaa ti gbe makirifoonu bọnu nibi to ti lọọ kọrin, ohun to si sọ ni pe oun ko le maa ṣe langbalangba kiri bii ọdọ, nitori ipo agba loun wa bayii, niwọn igba toun ti lawọn ọmọ ti gbogbo aye le pe ni ọdọ daadaa.

Bo ṣe forin wi i niyẹn o, ko si sẹnikan bayii to ba a fa a, nitori Pasuma naa ki i ṣe ọmọde mọ loootọ, oṣu to n bọ yii gan-an ni ọkunrin olorin fuji yii yoo pe ẹni ọdun mẹtalelaaadọta looke eepẹ.

Ṣa o, bi iroyin ọhun ti gba igboro kan pe niṣe ni awọn ọdọ yari pe awọn ko fẹ ko sọ ohunkohun, kia ni ọkunrin yii gba ori Instagiraamu ẹ lọ, to si fi fidio bọrọ ṣe jẹ sibẹ fawọn eeyan lati ri.

Ninu fidio kan to wa lori instagiraamu ẹ, bo ti ṣe yọ fila ẹ soke to n ki wọn, niṣe lawọn ọdọ kan n pariwo ‘No….no….no…’

Bakan naa ni fidio mi-in tun wa lori ikanni ọhun, nibi to ti n sọrọ, ohun to si sọ ni pe o di dandan ki a fopin si ipakupa tawọn SARS n pa awọn eeyan, atawọn iwa buruku mi-in tawọn ẹṣọ agbofinro n hu kiri.

Yatọ si fidio mejeeji yii, o to tun kọ ọ sori Instagiraamu rẹ pe “Emi naa darapọ mọ awọn ọdọ Naijiria lati sọ pe a gbọdọ fopin si awọn iwa ibajẹ, aṣeju ati iṣejọba buruku to fẹẹ ba aye orilẹ- ede yii jẹ
“Gẹgẹ bi ọmọ orilẹ-ede yii, ti ọjọ ori ẹ tun ju tawọn ọdọ lọ, ti mo tun jẹ ẹni to n wa ọjọ ọla rere fun Naijiria, ti mo si tun wa lara awọn eeyan ti a fi eto iṣakoso ijọba to dara dun, o jẹ ohun to buru gbaa, ti a ba la oju wa silẹ, ti eto iṣejọba ti ko le ko oriire kankan ba wa ba n tẹsiwaju lorilẹ ede wa. O yẹ ki a ta ko ijọba to le ṣakoba fun igbe aye awọn ọdọ, awọn to yẹ ki a maa wo gẹgẹ bii ọjọ ọla wa, ṣugbọn ti ala rere to yẹ ki wọn ni si toju wọn ja sofo.”
Alabi, ti sọ pe oun yoo tubọ maa satilẹyin fawọn ọdọ, bi wọn ti n ṣe n gbaiyanju lati sọrọ soke bayii, titi ti ohun wọn yoo fi gba gbogbo agbaye kan, ti igbese to yẹ yoo si waye lori ohun ti wọn  n beere fun.

Ki wahala too de ba ọkunrin olorin fuji yii pẹlu awọn ọdọ lawọn yooku ẹ ti wọn jọ jẹ gbajumọ nidii iṣẹ ọhun ti jade lati nawọ ifẹ si awọn ọdọ to n ṣewọde kiri.

Lara awọn onifuji ti wọn ti darapọ mọ awọn ọdọ ni: Saidi Oṣupa, Sule Alao Malaika, Ṣefiu Adio; bẹẹ lọrọ ọhun ko yọ awọn olorin mi-in bii Ṣeun Kuti, Smal Doctor, Eedris AbdulKareem ati bẹẹ bẹẹ lọ silẹ.

 

7 thoughts on “Awọn ọdọ pariwo ole le Pasuma lori nibi ti wọn ti n ṣewọde ta ko SARS l’Ekoo

  1. Oro yi koye kole to bayi pasuma ni kan ko ni gbajumo ti kosi nibi iwode yi ife ti awa odo ni si lofa ti won fi sebe tori won tife gboun re tipe tipe

Leave a Reply