Awọn ọdọ tinu n bi le olori awọn Fulani ati ẹran rẹ kuro ni Ojoku-Ikọtun, ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ni awọn ọdọ tinu n bi, le olori awọn Bororo darandaran, Alhaji Muhammadu, ati maaluu rẹ tefetefe kuro ni agbegbe Ojoku-Ikọtun, níjọba ibilẹ Ọyun, nipinlẹ Kwara.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe lati ilu Isẹyin, nipinlẹ Ọyọ, lawọn Bororo ọhun ti n bọ, ti wọn si n gbero lati fi Ilu Ojoku-Ikọtun ṣe ibujoko, sugbọn awọn ọdọ ilu fariga, wọn lawọn o le gba awọn ọdaran siluu, ni wọn ba le wọn danu patapata.

Ohun ti a ri gbọ ni pe ikọ ẹṣọ alabo aabo ara ẹni laabo ilu (Civil Defence) ni wọn da si ọrọ naa ti ko fi dogun, dọtẹ laarin awọn Bororo darandaran ati awọn ọdọ Ojoku-Ikọtun.

Agbẹnusọ ikọ ṣifu difẹnsi, Babawale, sọ pe olori awọn Bororo darandaran ọhun, Alhaji Muhammadu, ni ilu Lọkọja lawọn yoo mori le, nibi ti awọn mọlẹbi awọn tẹdo si.

Babawale ni awọn sin awọn Bororo ọhun atawọn maaluu wọn de Bode Ojoku si Ọfa, awọn si fa wọn le ẹsọ alaabo agbegbe naa lọwọ lati ṣe ohun to tọ pẹlu wọn.

Leave a Reply