Awọn ọdọ to n ṣewọde SARS kọ ounjẹ ti MC Oluọmọ gbe ranṣẹ si wọn

Faith Adebọla

Ni Furaidee, ọjọ Ẹti, ọsẹ yii, ni alaga awọn onimọto nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, gbe ọpolọpọ ounjẹ ati ohun mimu ranṣẹ si awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde ta ko SARS ni Alausa. Orukọ rẹ ni wọn kọ si omi mimu to wa ninu ounjẹ naa ti wọn fi ọkọ kan gbe ranṣẹ si wọn.

Bi awọn ọdọ yii ṣe ri ounjẹ naa ni wọn ti n pariwo pe awọn ko fẹ, awọn ko jẹ, nigba ti wọn mọ pe lati ọdọ ọga onimọto yii lo ti wa. Ariwo ti awọn mi-in si n pa ninu wọn ni pe awọn ko jẹ majele.

Niṣe ni awọn kan ninu wọn si n ju ike omi lu mọto ti wọn fi gbe ounjẹ naa wa.

Tẹ o ba gbagbe, ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni awọn janduku kan lọọ da iwọde awọn eeyan naa ru, ti wọn si ṣe awọn kan leṣe ninu wọn. Awọn ọdọ yii naka aleebu si MC, wọn loun lo ran awọn toogi wa, ṣugbọn ọga onimọto naa sọ pe oun ko lọwọ ninu rẹ, bẹẹ loun ko si ran ẹnikẹni lati lọọ da iwọde naa ru.

O jọ pe ohun to ṣẹlẹ yii lo mu ki MC fi ile pọnti, to si fọna roka, to ni ki wọn gb e e lọ fun awọn ti wọn n fẹhonu han yii lati fi han pe oun naa ṣatilẹyin fun igbogun ti iwa buruklu tawọn SARS n hu, ṣugbọn odi lo bọ si lara awọn to n fẹhonu han naa, wọn lawọn ko fẹ, awọn ko jẹ ounjẹ MC Oluọmọ.

Leave a Reply