Awọn ọdọ to n ṣewọde SARS ti gboro o, kaakiri ipinlẹ ni wọn ti dina pa

Awọn oniroyin wa

Kaakiri ipinlẹ ni ilẹ Yoruba, o fẹẹ ma si ibi ti iwọde ifẹhonu han ta ko awọn SARS yii ko ti i de. Ni ba a ṣe n sọ yii, gbogbo awọn oju ọna kaakiri ipinlẹ Eko, Ọyọ, Ogun, Ekiti ati awọn ilu mi-in kaakiri ni wọn ti di patapata.

Ni nnkan bii aago mẹfa aarọ ni awọn ọdọ yii ti bọ soju titi, ti wọn si di awọn oju ọna pa. Eyi ko yọ oju ọna marose to lọ lati ilu Eko si Ibadan silẹ. Awọn to fẹẹ jade ko rọna lọ, bẹ ẹ ni awọn to fẹẹ wọle ko le wọle.

Niṣe ni awọn ọdọ to n fẹhonu han yii da awọn oṣiṣẹ sẹkiteria to yẹ ki wọn bẹrẹ iṣẹ loni pada sile. Ọpọ wọn ni ko rọna kọja sibi iṣẹ, niṣe ni awọn to ba si jaja rọna lọ n pada sile wọn.

Lati ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni awọn ara ipinle Ogun ti kede ni tiwọn. Awọn ọdọ to n fẹhonu han yii ni lati aarọ lawọn yii ti bẹrẹ, nibi ileepo NNPC. Bẹẹ ni wọn ṣeto jijẹ mimu fun awọn to ba fẹẹ wa sibẹ. Gbogbo abẹ buriiji Mọlete, ti ile ijọba, Orita challenge ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ọdọ yii ti di pa.

Ohun ti wọn ṣaa n sọ ni pe awọn yoo ba ijọba Buhari mu nnkan nilẹ bi ko ba ṣe ohun ti awọn fẹ.

Leave a Reply