Aderounmu Kazeem
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ti pana awuyewuye to n lọ nipinlẹ naa lori bi awọn kan ṣe kọlu mọto rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, to si jẹ pe Ọlọrun lo ko ọkunrin naa yọ. O ni ki i ṣe awọn to n ṣe iwọde lo kọlu oun, awọn janduku, awọn ọmọ iṣọta ti oun ko mọ idi ti wọn fi ṣe bẹẹ lo wa nidii wahala to ku diẹ ko mu ẹmi oun lọ yii. Ninu atẹjade kan to fi ba gbogbo eeyan ipinlẹ Ọṣun sọrọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lo ti sọrọ naa.
Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ ẹ sọ lori iṣẹlẹ ọhun, o ni o ṣe ni laaanu pe awọn eeyan kan ku, ṣugbọn ki i ṣe mọto akọwọọrin oun lo pa wọn, nitori pe nibi tawọn mejeeji ọhun ti pade iku ojiji yii jinna daadaa sibi ti oun wa, ati pe iwọde jẹẹjẹ lawọn ọdọ ipinlẹ Ọṣun ṣe lọjọ naa, oun naa si ba wọn ṣe e.
Oyetọla fi kun un pe deede aago mejila ni ijanba akọkọ ṣẹlẹ, ọkada si lo pa ẹni naa, o si ti ṣẹlẹ tipẹ ki oun too de ibi ti awọn eeyan ti n ṣewọde.
Ijanba keji to gba ẹmi ẹni keji, gomina ni adugbo kan to n jẹ Ayepe lo ti waye, bii kilomita marun-un lo si fi jinna si Ọlaiya, nibi ti oun wa pẹlu awọn to n ṣe iwọde.
Gomina ni, “Ki Ọlọrun rọ ẹbi awọn to ku yii loju, bẹẹ la ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣewadii lori bi iku awọn eeyan ọhun ṣe waye.”
Lori awọn ti wọn kọlu ọkọ akọwọọrin ẹ, Gomina Isiaka Oyetọla ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo sọ pe ki i ṣe awọn ti wọn n ṣewọde kiri lo kọlu oun, bi ko ṣe awọn janduku tọọgi kan.
O ni, “Mo fẹẹ fi da awọn eeyan mi nipinle Ọṣun loju wi pe ki i ṣe awọn ọdọ to n ṣe iwọde ta ko oriṣiiriṣii iwa buruku tawọn ẹṣọ SARS n ṣe lo kọlu mi, awọn tọọgi kan ni. Lati agbegbe Alekuwodo, titi de Ọlaiya, la jọ fẹsẹ rin de, ti emi naa darapọ mọ wọn, bẹẹ la jọ n kọrin oriṣiiriṣi ni paapaa, nibi ti mo ti n ba wọn sọrọ lọwọ pe tiwọn ni ijọba ipinlẹ Ọsun n ṣe, asiko igba naa lawọn tọọgi kan kọlu wa, ti awọn ẹṣọ mi si sare gbe mi kuro nibẹ.
“Bi wọn ti ṣe kọlu mi lọjọ yẹn fi han pe wọn mọ-ọn-mọ ṣe e ni, bẹẹ ni mo ti gbe igbimọ kan dide bayii ti yoo ṣewadii lori iwa afojudi buruku yii.”
Gomina ti waa fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun balẹ pe eto aabo to peye yoo wa lori ẹmi ati dukia wọn, ati pe ijọba ko ni i faaye gba iwa janduku kankan nipinlẹ Ọsun.
Ọrọ di bo o lọ o yago lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, niluu Oṣogbo, nigba tawọn janduku tọọgi kan kọlu ọkọ akọwọọrin gomina, ti wọn si fi okuta atawon ohun ija oloro mi-in le e lere.
Bo tilẹ jẹ pe ori ko gomina ọhun yọ, ti ko si sẹni to fara pa ninu awọn to n tẹle e kiri, sibẹ mọto rẹ bajẹ, gbogbo gilaasi rẹ ni wọn fi okuta da batani si. Oriṣiiriṣi iroyin lo si gbalu kan ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye. Ohun tawọn kan n sọ ni pe eeyan meji ni gomina fi mọto ẹ pa danu lọjọ naa, ṣugbọn pẹlu alaye yii, o fi han pe ọkọ gomina kọ lo pa wọn, bẹẹ ni awọn to n ṣewọde SARS kọ lo kọlu u.