Awọn ọdọ tun dana sunle, ṣọọbu ni Bauchi, wọn lọmọbinrin kan sọrọ odi si Islam

Ọrẹoluwa Adedeji
Wahala mi-in tun ṣẹlẹ ni ilu kan ti wọn n pe ni Katangan-Waji, ni agbegbe ijọba ibilẹ Warji, nipinlẹ Bauchi, lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii. Ọmọbinrin kan ni wọn fẹsun kan pe o sọrọ odi si Anọbi nigba to n sọrọ nipa Deborah Samuel ti wọn pa nipinle Sokoto laipẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ahmed Wakili, gbe sita lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, lo ti sọ pe ọmọbinrin ẹni ogoji ọdun kan ti orukọ rẹ n jẹ Rhoda Jatau, to n ṣiṣẹ ni ẹka to wa ni ẹka iṣegun nijọba ibilẹ naa lo kọ ọrọ kan sori Facebook ti wọn lo tabuku ba ẹsin Islam.
Ibinu ọrọ ti wọn lo kọ ohun lawọn ọdọ ilu naa fi tu jade, ti wọn si bẹrẹ si i dana sun ile ati ṣọọbu nijọba ibilẹ naa.
Ile mẹfa, ninu eyi ti ile pasitọ kan wa ati ọpọlọpọ ṣọọbu ni wọn dana sun.
Alukoro fi kun un pe loju-ẹsẹ ni kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki awọn agbofinro lọ si awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ti alaafia si ti n jọba nibẹ.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ọdọ kan naa dana sun ọmọbinrin akẹkọọ ileewe olukọni Sheu Shagari College of Education to wa ni Sokoto, Deborah Samuel. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o sọrọ odi si Anọbi.

Leave a Reply