Awọn ọdọ yari, wọn lawọn o fara mọ bijọba ṣe fẹẹ ṣi Too-geeti Lẹkki pada bayii

Faith Adebọla, Eko

Bawọn ọdọ ṣe n fi aidunnu wọn han si bijọba ṣe n gbero lati ṣi Too-geeti Lẹkki, nipinlẹ Eko, pada, wọn ni erongba naa ta ko ipinnu awọn ati lẹta tawọn ti fi ranṣẹ ṣijọba lori ọrọ ọhun.

Yatọ si pe wọn lawọn o fẹ kijọba ṣi ibẹ, wọn ni bijọba ṣe fẹẹ fa akoso too-geeti ọhun le ileeṣẹ Lekki Concession Company (LCC) to ti n mojuto o latilẹ wa ko le seso rere, awọn o fara mọ ọn, awọn o si ni i fara mọ ọn. A gbọ pe ọmọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, iyẹn Ṣeyi Tinubu, lo ni ileeṣẹ LCC, oun ni alaṣẹ ati oludari rẹ.

Ọrọ yii jẹ yọ lọjọ Abamẹta, Satide yii, ninu lẹta kan tawọn ọdọ meji to n soju fun awọn ọdọ ipinlẹ Eko, Rinu Oduala ati Temitọpẹ Majẹkodunmi, buwọ lu lẹyin ijooko igbimọ to n gbọ awuyewuye ẹsun iwa aidaa ati ifiyajẹni ikọ ọlọpaa SARS tijọba ti fofin de.

Awọn ọdọ meji ọhun ni wọn n ṣoju awọn ọdọ ninu igbimọ to n gbọ ẹdun ọkan awọn araalu ti wọn ti foju wina abuku ati iya kan tabi omi-in latọwọ awọn ọlọpaa, ti wọn si n fẹ kijọba gbeja awọn.

Ninu lẹta tawọn ọdọ naa kọ, wọn ni aba tawọn ti mu wa lori ọrọ Too-geeti Lẹkki yii ko fara han rara ninu awọn aba ati ipinnu ti igbimọ to n gbọ ẹsun naa ka jade lọjọ Abamẹta.

Wọn ni ohun tawọn ti kọkọ sọ ṣaaju ni pe kijọba ṣi jẹ ki Too-geeti Lẹkki wa ni titi pa, kẹnikẹni tabi ileeṣẹ kan ma ti i bẹrẹ iṣẹ kan nibẹ, tabi gbowo lọwọ awọn onimọto titi ti ẹkunrẹrẹ iwadii yoo fi pari lori bi wọn ṣe ṣeku pa awọn kan lara awọn ọdọ to n ṣewọde ta ko ọlọpaa SARS lalẹ ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja (2020), ti wọn si ṣe ọgọọrọ awọn mi-in leṣe, pẹlu gbogbo ariyanjiyan to waye lẹyin naa. Wọn ni gbogbo hulẹhulẹ otitọ to farasin gbọdọ han faraye lori iṣẹlẹ ọhun, tori iṣẹlẹ naa ni lajori ohun to fa ọgọọrọ ajalu to ṣẹlẹ nigba naa. Apa kan lẹta awọn ọdọ naa ka pe:

“Awọn ọdọ to n ṣoju ọdọ yooku ninu igbimọ oluṣewadii si ẹsun awọn araalu ti ikọ ọlọpaa SARS fiya jẹ ati iṣẹlẹ Too-geeti Lẹkki n fi asiko yii sọ kedere pe awa o fara mọ ipinnu igbimọ yii lati jẹ ki wọn da Too-geeti naa pada fawọn to n moju to o tẹlẹ.

“A fẹ lati ran awọn eeyan leti pe tori awọn nnkan marun-un ta a beere lọwọ ijọba, eyi to mu ki iwọde ta ko iwakiwa awọn ọlọpaa waye jake-jado orileede yii, lo mu ki wọn gbe igbimọ yii kalẹ. Tori bẹẹ, ipinnu eyikeyii ti igbimọ yii ba ṣe lai gba ero awọn ọdọ yẹwo ti ta ko ofin ati ilana ti wọn fi gbe igbimọ naa kalẹ.

“Awa ọdọ ti jẹ ki ero wa ṣe kedere si igbimọ yii ati si ileeṣẹ LCC to kọwe pe awọn fẹẹ lọọ bẹrẹ iṣẹ pada ni Too-geeti naa, a si ran igbimọ naa leti pe ko gbọdọ si ojooro kan ninu awọn ipinnu wọn.

“A ti ri i pe ileeṣẹ LCC ko jẹ ki awọn oluwadii imọ-ijinlẹ ti igbimọ yii yan lanfaani si awọn akọsilẹ ati kamẹra wọn lati le fidi otitọ ohun to ṣẹlẹ mulẹ titi di asiko yii, bẹẹ ni ileeṣẹ naa n gbe safa (servers) wọn, aworan kamẹra atanilolobo wọn, atawọn nnkan to le tu aṣiri wọn.

“Bawo waa ni igbimọ yii ṣe fẹẹ paṣẹ pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn ni Too-geeti yii bii ẹni pe ọwọ wọn mọ, wọn o lẹbi, tabi bii pe ọrọ ohun to ṣẹlẹ nigba naa lọhun-un ko kan wọn.

“Latari eyi, ero wa ko ruju rara, a fẹ ki Too-geeti Lẹkki wa ni titi na, labẹ iṣọ igbimọ oluwadii yii, titi ti wọn fi maa tu iṣu ọrọ naa desalẹ ikoko.

“Ẹ ma ṣi wa gbọ o, ki i ṣe pe a fẹẹ ta ko ipinnu igbimọ yii o, ṣugbọn a fẹ ki gbogbo aye mọ pe a o fara mọ awọn ipinnu pato kan, ki idi ti a ko ṣe fara mọ ọn si wa lakọọlẹ. Gbogbo ohun ti a n ja fun ni ki idajọ ododo fidi mulẹ fun awọn ti wọn rẹ jẹ tabi ṣaida si.”

Leave a Reply