Awọn ogoji agbẹ ti Boko Haram pa ko gba aṣẹ ki wọn too lọ sinu oko wọn – Ọmọọṣẹ Buhari

Aderounmu Kazeem

Pupọ ninu awọn ọmọ orilẹ-ede yii ni inu wọn ko dun rara lori ọrọ ti Garba Shehu, oluranlọwọ nipa eto iroyin fun Aarẹ  Muhammadu Buhari, sọ lori bi awọn Boko Haram ṣe pa awọn ogoji agbẹ onirẹsi nipinlẹ Borno.

Ohun to bi awọn eeyan ninu ni bi Garba Shehu ṣe sọ pe, awọn ni wọn fa iku ojiji to pa wọn, nitori ti awọn agbẹ naa ko gbaṣẹ lọwọ awọn ṣọja ki wọn too lọ soko ti wọn ti lọọ pa wọn.

O ni kani awọn ṣọja to n ṣọ agbegbe naa ba mọ pe awọn agbẹ onirẹsi  wa loko, yoo ṣoro fawọn janduku a-gbebọn-rin lati pa wọn, nitori eto aabo yoo wa fun wọn.

Bakan naa lo sọ pe agbegbe Lake Chad Basin ki i ṣe ibi ti eeyan le ku giiri lọ, nitori awọn janduku afẹmi-ṣofo pọ nibẹ rẹpẹtẹ.

Lori tẹlifiṣan BBC lo ti sọrọ yii, lojuẹsẹ naa lawọn eeyan orilẹ-ede yii ti kọlu u, ti wọn si sọ pe ọrọ to sọ yii, bii alailaanu ati ika ọdaju eeyan ni.

Ọkan lara ọmọ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Shehu Sani, ninu ọrọ ẹ lori ikanni abẹyẹfo ẹ ti fun oṣiṣẹ Buhari yii lesi, nibẹ naa lo ti bu ẹnu atẹ lu ̀ọrọ ti Mallam Garba Shehu sọ.

Sanni sọ pe ọrọ buruku gbaa ni oluranlọwọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari yii sọ. O ni ni bayii, ọrọ Naijiria ti di pe ti eeyan ba fẹẹ lọọ gẹrun lasan, o ti di ki o maa gbaṣẹ lọwọ Ṣọja, tabi ti eeyan ba fẹẹ lọ ra ọja nile itaja nla. O loun mọ bayii pe nitori ohun ti Garba Shehu sọ yii, niṣe lawọn eeyan yoo bẹrẹ si ni i beere fun iwe aṣẹ ki wọn too le ṣe ohukohun ni Naijiria.

 

Leave a Reply