Ofin ọkada: Ijọba Eko gbẹsẹ le ọkada mẹẹẹdogun n’Ikorodu

Adewumi Adegoke

Awọn ọlọkada ti ijọba Eko fofin de ko mu ọrọ naa ni kekere rara pẹlu bi wọn ṣe ṣakọlu si awọn ọlọpaa to n mu awọn to ba lufin ijọba lori ọrọ gigun ọkada lawọn ibi ti ko bofin mu.
Awọn araalu ni wọn ta awọn agbofinro lolobo pe awọn ọlọkada naa ṣi n ṣiṣẹ lawọn agbegbe yii lọwọ alẹ, eyi lo fa a tawọn agbofinro naa fi lọ si adugbo yii ni alẹ ọjọ Ẹti, Furaide, to ṣẹṣẹ pari yii. Ṣugbọn niṣe lawọn ọlọkada atawọn ọmọ ita kọju ija si wọn lasiko ti wọn fẹẹ fipa gba ọkada tawọn eeyan naa n gbe gba oju ọna ti ijọba ti fofin de ọhun, n lọrọ ba di bo o lọ o yago.
Lasiko akọlu nnaa ni aọn agbofinro gba ọkada bii mẹẹẹdogun, ti wọn si mu awọn ọmọọta bii aadọta.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, sọ pe awọn araalu ni wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo pe awọn ọlọkada naa ṣi n yọ iṣẹ ṣe lawọn agbegbe ti wọn ti fi ofin de wọn pe wọn ko gbọdọ de mọ. Eyi lo fa a tawọn eeyan awọn fi lọ sibẹ, ṣugbọn niṣẹ lawọn ọlọkada yii atawọn ọmọọta kọju ija si awọn agbofinro naa.
O ni niṣe lawọn maa lọọ lọ ọkada tawọn gba lọwọ wọn yii lẹbulẹbu bii elubọ.

Leave a Reply