Awọn ololufẹ Samuel Kalu to ko Korona wọle adura fun un

Oluyinka Soyemi

Awọn ololufẹ agbabọọlu ilẹ Naijiria to n ṣe bẹbẹ ni Bordeaux, ilẹ France, Samuel Kalu, to ko arun Koronafairọọsi ti bẹrẹ adura nla fun un.

Ẹni ọdun mejilelogun naa ni ikọ Super Eagles keji to ko arun naa lẹyin Paul Onuachu to n gba bọọlu jẹun ni Genk, nilẹ Belgium.

Lati igba ti Kalu ti pada si France nigba to kuro ni Naijiria laipẹ yii lo ti wa ni igbele, Bordeaux si kede pe agbabọọlu awọn kan ti ko arun naa, bo tilẹ̣ jẹ pe wọn ko darukọ rẹ.

Iwadii fi han pe igbele ti Kalu wa ko jẹ ko ṣe awọn igbaradi tawọn ọmọ kilọọbu rẹ n ṣe, ati pe ọjọ kẹfa, oṣu yii, lo ko arun naa.

Ṣugbọn ireti wa pe ara Kalu yoo ti ya ko too di ipari oṣu yii ti yoo lanfaani lati darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ.

GBS Academy, ilu Jos, ni Kalu ti kọ ẹkọ nipa bọọlu ko too kọja si ilẹ Slovakia ati Belgium, nibi to gba de France to wa lọwọlọwọ.

Ọdun 2018 ni ogo rẹ gbera ni Eagles nigba to gba bọọlu wọle nibi ifẹsẹwọnsẹ Naijiria ati Libya, nibi ti Eagles ti yege pẹlu ami-ayo mẹrin si odo.

Leave a Reply