Awọn ọlọpaa ṣi n wa Roselyn at’alejo ẹ tawọn kan ji gbe l’Ọfada

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣi n wa obinrin kan, Roselyn Edusi, ati alejo rẹ ọkunrin ti awọn kan jọ ji gbe nitosi Ọfada, lọjọ Satide to kọja.

Oniṣowo ni Roselyn, ile faaji kan lo n mojuto lagbegbe Omu, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun. Lọjọ Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un yii, ni wọn ni obinrin yii ati alejo rẹ toun jẹ ọkunrin, lọ si oko kan lagbegbe Ọfada, nipinlẹ Ogun kan naa, nibẹ ni wọn ti bọ sọwọ awọn ajinigbe to gbe awọn mejeeji lọ ti ẹnikẹni ko si gburoo wọn lati ọsan ọjọ naa.

Eko ni wọn ni ọkunrin to wa Roselyn wa ti wa, nigba to de ọdọ obinrin naa tan ni wọn jọ lọ si Ọfada ti wọn ti bọ sọwọ ajinigbe.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fidi ẹ mulẹ pe awọn ṣi n wa awọn mejeeji yii. O ni awọn yoo ri awọn to gbe wọn mu, awọn yoo si ri i daju pe awọn gba Roselyn ati ọrẹ ẹ silẹ.

Oyeyẹmi sọ pe awọn ajinigbe naa ko ti i ba ẹnikẹni sọrọ pe boya wọn fẹẹ gbowo ki wọn too tu wọn silẹ, o ni iṣẹ ti n lọ gidi lori ijinigbe naa ṣa.

Leave a Reply