Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori alaga ẹgbẹ APC ti wọn pa l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kede pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn agbebọn ṣe pa Oloye Gbenga Ọgbara to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakunmọsa, nipinlẹ Ọṣun.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ninu ile ọkunrin naa. Bi gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ṣe bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa ni alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọọdun, sọ pe iwa ika gbaa ni awọn to da ẹmi ọkunrin naa legbodo hu.
Gẹgẹ bi Alaroye ṣe gbọ lẹnu ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa, Arẹgbẹṣọla Ọgbara, ẹni ti oun naa n gbatọju lọwọ nileewosan bayii, ọkada ni awọn agbebọn naa gun wa sile wọn lalẹ ọjọ naa.
O ni wọn beere baba oun, oun ati iya oun si sọ pe baba oun wa ninu ile, o ni bi baba oun ṣe ṣilẹkun pe ko yọju si wọn ni wọn dana ibọn bolẹ.

Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe ikun ni ibọn ti ba baba oun, nigba ti ibọn ta ba oun naa (Arẹgbẹṣọla) ni apa.

Amọ ṣa, Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe oku baba ẹni ọdun mejilelọgọta naa ti wa nile igbokuu-si Ọsibitu Wesley Guild, niluu Ileṣa, nigba ti iyawo ati ọmọ rẹ n gbatọju lọwọ nileewosan kan naa.
O ni kọmiṣanaa ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti da awọn ọlọpaa sagbegbe naa, ati pe ko le pẹ rara ti aṣiri awọn to huwa naa yoo fi tu.

Alaga ẹgbẹ APC l’Ọṣun, Famọọdun ṣapejuwe iku Oloye Ọgbara gẹgẹ bii ọfọ ati ajalu nla fun ẹgbẹ naa, o si ke si awọn agbofinro lati wa awọn to ṣiṣẹ laabi naa jade.

Bakan naa, Gomina Oyetọla, ẹni to sọrọ nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Ismail Omipidan, ni gẹgẹ bi ijọba to bikita fun ẹmi ati dukia awọn araalu, ijọba ti paṣẹ fun awọn agbofinro lati ṣawari ẹni to ṣeku pa ọkunrin naa kiakia.

O ke si awọn araalu lati ni suuru, ki wọn maṣe gbero lati gbẹsan lọwọ ara wọn, ki wọn fun awọn agbofinro lanfaani lati ṣewadi wọn, ki awọn ti wọn huwa naa le fimu danrin.

Oyetọla kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi ati ojulumọ oloogbe naa, o si gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.

Leave a Reply