Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, Tunde Mobayọ, ti sọ pe awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ko sa kuro lẹnu iṣẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe ro latari iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko ikọ SARS, eyi tawọn janduku sọ di rogbodiyan.
Lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni ọga agba ọlọpaa naa sọrọ nipasẹ Alukoro ileeṣẹ naa, Sunday Abutu.
Ikede naa waye lẹyin tiroyin gba igboro pe awọn ọlọpaa ko si loju titi mọ, bẹẹ ni wọn ko rin kiri bii ti tẹlẹ latari ibẹru pe awọn janduku le ṣakọlu si wọn.
ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn ọlọpaa ti dinku loju popo ati lawọn ibudo ti wọn maa n duro si tẹlẹ, koda, awọn to n dari ọkọ gan-an ṣẹṣẹ pada sẹnu iṣẹ laipẹ yii ni.
Ṣugbọn Mobayọ ni awọn wa digbi lati pese eto aabo to fẹsẹ mulẹ, bẹẹ lawọn yoo ṣiṣẹ awọn nilana ofin.
O waa kilọ fawọn ọdaran pe ko si aaye fun wọn l’Ekiti, bẹẹ lo fọkan awọn eeyan balẹ pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn.