Awọn ọlọpaa Eko n wa Adeyẹmi o, wọn lo gun ọkọ ale ẹ lọbẹ pa

Awọn ọlọpaa Eko ni awọn n wa Adekunle Adeyẹmi bayii bayii o, ẹsun ti wọn si n tori ẹ wa a ni pe wọn lo gun ọkọ ale rẹ ti wọn n pe ni Chisom pa. Agbegbe Grammar School ni Ikorodu ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ nipari oṣu keje, lati igba naa lawọn ọlọpaa yii si ti n wa afurasi naa ti wọn ko ri i.

Ile kan naa ni Arinze Onuoha pẹlu iyawo rẹ ati Adeyẹmi jọ n gbe ni Red Block Street, nibẹ naa si ni  ẹnu ti bẹrẹ si i kun Adeyẹmi pe o n mu nnkan jẹ lara Chisom, iyawo Arinze. Ọrọ yii lo di ariyanjiyan rẹpẹtẹ, ni Adeyẹmi ba fa ọbẹ alaṣoro yọ, o si gun Arinze lapa osi ni igbaaya rẹ, nigba ti wọn yoo si fi gbe tọhun de ọsibitu, o ti ku pata.

N lawọn ọlọpaa ba gbọ ọrọ yii ni wọn sare wa sile naa, ṣugbọn ki wọn too de, gbogbo awọn araale ti sa lọ, ko si sẹni to tilẹ gburoo Adeyẹmi to da kinni naa silẹ rara. Iyẹn lawọn ọlọpaa ṣe ni awọn n wa Adeyẹmi, awọn si ti bẹrẹ ifimufinlẹ lori bi awọn yoo ṣe ri i.

Leave a Reply