Awọn ọlọpaa fẹẹ mu ọlọkada ni wọn ba le e sẹnu ọkọ to n bọ, niyẹn ba tẹ ẹ pa

Faith Adebọla

Ọlọkada kan tawọn eeyan o ti i mọ orukọ rẹ ti pade iku ojiji nitosi ileepo National, nibudokọ Ikẹja-Along, to wa ni titi marosẹ Oṣodi si Sango, wọn lawọn ọlọpaa to n le e lati mu un lo jẹ kọkunrin naa ko sẹnu ọkọ to n bọ, niyẹn ba lọ ọ mọlẹ, o ku fin-in fin-in.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn oṣiṣẹ amuṣẹya (task force) lẹka to n ri si ibajẹ ayika ati awọn ẹsun akanṣe (Lagos State Environmental and Special Offenses) ni wọn n ṣiṣẹ lọwọ lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, wọn n mu awọn ọlọkada to n gba ọna marosẹ naa ati awọn to gba ọna ti ko yẹ ki wọn gba, tori titi marosẹ naa wa lara awọn ọna tijọba Eko ṣofin p’awọn o fẹẹ ri ọlọkada ero kan lori ẹ.

Akọroyin Punch ti wọn ba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Samuel Akintunde, ni iṣẹlẹ naa ṣoju oun, o ni lati nnkan bii aago mọkanla owurọ lawọn taskforce naa ti n mu awọn ọlọkada to n gbero kọja lọna marosẹ naa, ati pe niṣe ni wọn n le wọn mu, tagidi-tagidi ni wọn fi n mu wọn.

O ni oloogbe yii ko gbero, boya o si ti ja ero rẹ silẹ ni, ṣugbọn o gba ọna marosẹ ọhun, ni ọlọpaa kan ba le e mu bo ṣe n sa lọ.

Bo ṣe wi, o ni ọlọpaa naa bu ọkada rẹ so latẹyin, o si gbọn ọkada naa jigijigi mọ ọn nidii, ni oloogbe naa ba re bọ soju titi, o si ṣe kongẹ asiko ti ọkọ bọọsi kan n ba ere buruku bọ loju ọna keji marosẹ naa nibi tọlọkada yii ja bọ si, bọọsi naa ko ri’bi pẹwọ si rara, niṣe lo gori ọlọkada naa, to si pa a loju ẹsẹ.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o mu kawọn ọlọkada fariga, ti wọn fibinu dana soju titi naa, wọn bẹrẹ si i sun taya, wọn fẹẹ ṣoro fawọn ọlọpaa naa, wọn lọpẹlọpẹ awọn ṣọja ti wọn sare de’bẹ lati Cantonment wọn to wa lagbegbe Ikẹja, ti wọn si bomi pana rogbodiyan to ṣẹlẹ ọhun, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti gbe oku naa lọ si mọsuari kan n’Ikẹja.

Ọgbẹni Fẹmi Mọliki, agbẹnusọ awọn ikọ amuṣẹya naa sọ pe oun ko ti i le fidi rẹ mulẹ boya awọn oṣiṣẹ awọn lo ṣokunfa iṣẹlẹ yii, tori ko daju pe wọn jade fun mimu awọn ọlọkada lọjọ Satide ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ko ti i fesi si atẹjiṣe ta a fi sọwọ sori foonu rẹ titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Leave a Reply