Awọn ọlọpaa fibọn fọ mi lẹyin, wọn sọ mi di arọ, n ko si le bimọ mọ- Ọlasunkanmi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Awọn eeyan ti ko mọ Ọgbẹni Ọlasunkanmi Fagbemi ri fẹrẹ le maa ba a sunkun nigba ti ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) naa n ṣalaye bawọn ọlọpaa ṣe yinbọn mọ ọn lọdun 2010, to si ṣe bẹẹ di ẹni ti ko le fẹsẹ ara ẹ rin mọ, ti ko si tun le fun obinrin kankan loyun mọ laye.

Kootu Majisireeti Iṣabọ, l’Abẹokuta, ni Ọlasunkanmi ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si i. Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, lo rojọ naa niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ awọn ti ọlọpaa ti fiya jẹ ri lọna aitọ.

Ọkunrin naa jokoo ninu aga to fi n ṣe ẹsẹ rin ( Wheel chair), o si ṣalaye pe, ‘’Mo n lọ s’Ibadan lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2010, inu mọto ero ni mo wa ni nnkan bii aago meje alẹ, nigba naa ni awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Fidiwọ si Alapako, ni marosẹ Eko s’Ibadan, da mọto wa duro.

‘’Wọn gba ọndirẹdi naira lọwọ dẹrẹba wa, wọn si ni ko paaki mọlẹ daadaa kawọn le fun un ni ṣenji ọgọrin naira (#80).

‘’Lẹyin ti dẹrẹba paaki tan, o sọkalẹ lati lọọ gba ṣenji rẹ, bi ọlọpaa kan to wa lodi-keji ọna ṣe yinbọn mọ mọto wa niyẹn. Ibọn yẹn ba mi lọrun, o si lọ si isalẹ eegun ẹyin mi. Nigba tawọn ọlọpaa naa ri ohun to ṣẹlẹ, niṣe ni wọn sa lọ.

‘’Mi o mọ ohun to n ṣẹlẹ mọ, ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo to wa n’Ibadan (UCH), ni dẹrẹba atawọn ero ọkọ gbe mi lọ. Wọn da mi duro sọsibitu naa lati ṣiṣẹ abẹ, ọjọ kẹrin ni wọn too ri ọta ibọn naa yọ lara mi.

‘’Mo n mura lati ṣegbeyawo nigba naa ni, ṣugbọn lẹyin iṣẹlẹ yii, ko ṣee ṣe mọ, nitori awọn dokita sọ fun mi pe mi o le fun obinrin kankan loyun mọ, afi ti mo ba lo ilana ọmọ bibi ti wọn n ṣe lasiko yii, ti wọn yoo gba nnkan ọmọkunrin mi, ti wọn yoo si gbe e sinu obinrin. Mi o ti i fẹyawo latigba naa, bẹẹ ni mi o ti i bimọ kankan’’

Fagbemi loun ti kọwe si gbogbo ẹka to yẹ ko gbọ nipa iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ko so eso rere. O royin owo buruku to ti na nitori ati ri alaafia, ati bo ṣe jẹ pe wọn ti gbe oun lọ si India fun itọju, ṣugbọn lẹyin gbogbo ẹ naa, oun ko le fẹsẹ oun rin mọ, inu ṣia onirin yii naa loun n wa. Bẹẹ, ọlọpaa lo sọ aye oun di nnkan mi-in, toun ko le da nnkan kan ṣe mọ.

Alaga igbimọ yii, Adajọ Solomon Olugbemi, sọ pe awọn yoo kọ lẹta si kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, awọn to yẹ ko waa jẹjọ lori ọrọ yii yoo si yọju.

O sun igbẹjọ si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun 2021.

Leave a Reply