Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Awọn ọna mi-in tawọn eeyan ko fọkan si lawọn ajinigbe n lo bayii lati ji eeyan gbe, diẹ ninu ẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ti wọn ni karaalu tete mọ pe ewu n bẹ loko longẹ ni ọrọ aabo da bayii o.
Akọkọ ninu awọn ọna tuntun naa ni pe awọn ajinigbe ti n fara pamọ sawọn ibi to maa n da paroparo, ojiji ni wọn yoo yọ si ẹni ti ko ṣọ wọn, ṣugbọn ti awọn ti n ṣọ irin rẹ tipẹ.
Bi wọn ba ti ri ẹni naa to n bọ ni wọn yoo da a lọna, ti wọn yoo gba gbogbo ohun to ba ni lọwọ, wọn si le gbe e lọ ti wọn yoo maa beere owo nla lọwọ awọn mọlẹbi ẹ ki wọn too tu u silẹ. Fun idi eyi, wọn ni kawọn eeyan ṣọra fun irin lawọn ibi to ba paroparo.
Ọna keji ni ti awọn ọlọkada ti wọn yoo ti gbe ero kan sẹyin tẹlẹ, ti wọn yoo maa pe ero mi-in lati ṣikẹta wọn lori ọkada.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye pe awọn ajinigbe maa n ṣe bii ọlọkada, ti wọn yoo maa gbe ọkada kiri bii pe wọn n wa ero nitootọ. Bẹẹ, ero to ti jokoo lakọọkọ yii ki i ṣe ero tootọ, ajinigbe ti yoo ti fi oogun oorun pa ẹyin aṣọ rẹ ni.
Bi ero tootọ ti ko dakan mọ ba ti gun ọkada ni yoo fa oogun oorun to ti wa lara ẹni to ti jokoo tẹlẹ naa simu, oorun yoo bẹrẹ si i kun un lori ọkada naa lẹsẹkẹsẹ ni. Alẹ lo ni wọn saaba maa n ṣe eyi, bi wọn yoo ṣe wa ero naa lọ sibi ti wọn yoo ti sọ ọ di ohun ti wọn yoo fi pawo ni tiwọn niyẹn.
Fun idi eyi, wọn ni keeyan fi ọpọlọ ṣe e to ba di dandan lati gun ọkada to ti gbe ero kan tẹlẹ., ki kaluku maa woju daadaa.
Ọna kẹta ti wọn n gba jiiyan gbe ni ti awọn to n rin irin alẹ. Oyeyẹmi ṣalaye pe awọn ajinigbe ti n dọdẹ awọn oniṣowo ọkunrin ati obinrin ti wọn maa n pẹ ki wọn too kuro ni ṣọọbu wọn lalẹ. O ni kawọn ọlọja ṣọra fun irin alẹ gbere bo ti wu ko mọ, nitori yatọ si pe wọn le gba gbogbo ohun ti wọn ti ko jọ lataarọ lọwọ wọn, awọn ajinigbe tun le gbe wọn sa lọ ti yoo di pe awọn eeyan wọn ni yoo maa dawo ti wọn yoo fi gba wọn silẹ.
Awọn to n jiiyan gbe yii ko sun rara gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, wọn ni ojumọ kan, ara kan, ni wọn n da pẹlu ijinigbe yii.
Ẹ oo ranti pe ọsẹ to kọja yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede pe ọrọ aabo ti kuro ni ti awọn agbofinro nikan lasiko yii, wọn ni onikaluku ni ko ṣọ ara ẹ, keeyan ma huwa tabi rin irin ti wọn yoo fi ji i gbe ni koko o.