Awọn ọlọpaa lẹtọọ lati gbe ibọn, ki wọn le fi daabo bo araalu lọwọ ewu-Adamu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọga agba patapata fun ileesẹ ọlọpaa orileede yii, Adamu Muhammed ti gba awọn ọmọọsẹ rẹ nimọran lati gbagbe gbogbo rogbodiyan to suyọ lasiko iwọde SARS to kọja, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ wọn lakọtun.

Arọwa yii waye ninu ọrọ iyanju ti ọga ọlọpaa ọhun ba awọn ọmọ abẹ rẹ sọ lasiko abẹwo ọlọjọ kan to ṣe si ipinlẹ Ondo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.

O ni inu oun dun pupọ fun ọwọ akọsẹmọsẹ tawọn ọlọpaa fi mu ọrọ iwọde naa, nitori pe ohun tawọn to ṣagbatẹru rẹ n reti ni pe kawọn ọlọpaa sina ibọn fun ọgọọrọ awọn to n ṣewọde, ki wahala nla le tipa bẹẹ ṣẹlẹ.

O ni imọ wọn to ja ṣofo ni wọn ṣe ru awọn janduku kan soke lati ja iwọde alaafia naa gba mọ awọn ọdọ lọwọ, ti wọn si n ba dukia ijọba ati tawọn eeyan jẹ.

Adamu ni ki i ṣe gbogbo ọlọpaa ni wọn n huwa ọdaran, o ni ọpọ wọn lo n ṣiṣẹ naa ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin orileede yii, leyii to ṣokunfa bi Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ awọn gomina ṣe ṣatilẹyin to yẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa

O ni awọn ọlọpaa lẹtọọ lati gbe ibọn ki wọn si fi daabo bo dukia awọn araalu ati ẹmi ara wọn lasiko ewu, ṣugbọn eewọ patapata ni fun eyikeyii ninu wọn lati yinbọn pa alaisẹ labẹ akoso bo ti wu ko ri.

Fun imọriri awọn to ku, atawọn ti wọn fara pa lasiko rogbodiyan iwọde SARS, o ni ijọba apapọ ti buwọ lu igbega fun gbogbo awọn ọlọpaa, bẹẹ ni wọn si ti ṣe afikun sowo-osu ti wọn n gba.

O rọ awọn agbofinro ọhun ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn pẹlu igboya nitori pe ijọba ti ṣetan ati ṣatilẹyin to yẹ fun wọn.

Leave a Reply