Awọn ọlọpaa n wa Albert to bẹ ọmọ rẹ lori ni Gbọngan

Florence Babasola, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti n wa Albert Ọlapọsi, ẹni to bẹ ọmọ bibi inu rẹ lori laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Gbọngan, nipinlẹ Ọṣun.

ALAROYE gbọ pe ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn ni Albert, iṣẹ mẹkaniiki lo n ṣe, o si ti pẹ to ti mu ọmọ naa, Mercy, lọ sọdọ iya rẹ lagbegbe Oke-Oje, niluu Gbọngan, kan naa.

Laaarọ ọjọ Aje ni Albert kuro ninu ile to n gbe ni Oke-Ẹlu, o si lọ sọdọ iya rẹ, ko pẹ to debẹ niya agba naa figbe ta, kawọn araadugbo si too pe jọ, Albert ti sa lọ.

Ṣe ni wọn n wo oku Mercy, ọmọ ọdun marun-un nilẹ nibi ti baba rẹ bẹ ori rẹ si, wọn si lọọ pe awọn ọlọpaa ilu Gbọngan.

Wọn kọkọ gbe oku Mercy lọ si agọ ọlọpaa, lẹyin naa ni wọn gbe e lọ sile igbokuu-si ti OAUTHC, niluu Ileefẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari Albert, o ni nigba ti awọn ba ri i ni yoo sọ nnkan to ri to fi ṣe bẹẹ.

Leave a Reply