Ọlọpaa n wa mọlẹbi ọmọbinrin ti wọn ba oku ẹ lotẹẹli kan ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọmọbinrin kan ti wọn ko ti i mọ ibi to ti wa, ni wọn ba oku rẹ nileetura kan, Premium Diamond, to wa ni agbegbe Adewọle, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun Ilọrin (West)  nipinlẹ Kwara.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii. O lobinrin ti wọn pa sileetura ọhun ni wọn o ti ri ẹnikẹni ko waa beere rẹ, ati pe awọn Dokita ti ṣe ayẹwo oku naa ti gbogbo ara rẹ ṣi pe pẹrẹpẹrẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti waa kede pe gbogbo obi ati alagbatọ ti wọn o ba ri ọmọbinrin wọn bẹrẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, ki wọn wa si ẹka to n ri si ọrọ oku, lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, lati wo oku ọmọbinrin ọhun, ki wọn le gba oku wọn.

Nigba ti Ọkasanmi n ṣalaye lori iṣẹlẹ naa, o ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa yii, ni arakunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ọlamilekan Hanafi to jẹ alaamojuto ileetura Premium Diamond, to wa ni Adewọle, niluu Ilọrin, pe ileesẹ ọlọpaa, to si salaye pe ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Adegboyega James, (No 12, Okelewo Street, Ẹdẹ) nipinlẹ Ọsun, waa gba yara, lẹyin to gba a tan lo jade lọ, nigba to de pada loun pẹlu ọmọbinrin kan jọ pada de lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn nigba to di owurọ ọjọ keji ti awọn ko gbọ nnkan kan ninu yara naa lawọn lo kọkọrọ miiran lati ṣilẹkun, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe oku obinrin yii nikan lawọn ri ninu yara, awọn o si mọ igba ti ọmọkunrin ọhun sa lọ. Lẹyin iwadii ni awọn too mọ pe ayederu ni adirẹsi to fi silẹ.

 

Ọkasanmi ni Kọmiṣanna ọlọpaa, Mohammed Lawal Bagega, ti paṣẹ pe ki wọn mu awọn to n sakoso ileetura ọhun fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Leave a Reply