Awọn ọlọpaa n wa Patrick ti wọn lo lu iyawo ẹ pa l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ ọkunrin kan, Ikechukwu Patrick, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o lu iyawo rẹ, Christianah Patrick, pa sinu ile wọn to wa niluu Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Ninu alaye ti ẹgbọn oloogbe ọhun, Blessing Chidi, ṣe fun wa, o ni o ti le logun ọdun ti aburo oun ati ọkọ rẹ ti n gbe pọ gẹgẹ bii ọkọ ati aya, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe pe awọn mejeeji fẹ ara wọn niṣu lọka. Ọmọ mẹrin lo ni wọn ti bi fun ara wọn, ti eyi akọbi si ti n lọ si bii ọmọ ọdun mọkandinlogun.

O ni igba kan wa ti awọn ẹbi gba obinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa nimọran pe ko ko kẹru rẹ jade latari ilukulu ti ọkọ rẹ maa n lu u ni gbogbo igba.

Aigbọran rẹ si awọn ẹbi lẹnu lo ni o pada sọ ọ dero ọrun ọsan gangan.

Abilekọ Chidi ni oun wa niluu Ọwọ, nibi ti oun fi ṣebugbe laaarọ ọjọ kẹẹẹdogun, osu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, nigba ti ọkan ninu awọn ọmọ oloogbe to porukọ rẹ ni Precious pe oun sori aago pe baba awọn ti lu iya oun daku.

Ọmọde yii sọ fun un pe alẹ ọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa, ni ija nla kan sọ laarin awọn mejeeji latari bi Patrick ṣe kọ lati fun iyawo rẹ lowo ounjẹ to beere fun lasiko to fẹẹ jade nile laaarọ ọjọ naa.

Gẹgẹ bi alaye ti Precious ṣe, o ni asiko ti wọn n ja yii ni Patrick to jẹ baba awọn fi irin lu Christianah daadaa, to si tun fun un lọrun titi to fi daku mọ ọn lọwọ.

Wọn ti gbe iya ọlọmọ mẹrin ọhun sinu ọkọ tan laaarọ ọjọ keji ko le lọọ gba itọju nile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ ki wọn too ṣakiyesi pe o ti ku.

Wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti, awọn ni wọn si gbe oku oloogbe ọhun lọ si mọsuari, nibi ti wọn tọju rẹ si lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Ko ṣẹni to le sọ pato ibi ti ọkọ obinrin naa wọlẹ si lati igba naa, nitori pe ni kete to ti gbọ iroyin iku iyawo rẹ lo ti sa lọ.

Leave a Reply