Awọn ọlọpaa n wa Portable, olorin Zaa Zuh, l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ti gbajugbaja olorin Zaa Zuh nni, Habeeb Okikiọla, tawọn eeyan mọ si Portable, ba mọ iwọn ara ẹ, ko yaa fẹsẹ ara ẹ rin wa solu-ileeṣẹ wọn to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lati waa dahun ẹsun iwa ọdaran kan ti wọn fi kan an, aijẹ bẹẹ, wọn lọkunrin naa yoo ri pinpọn oju ijọba ni.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Kẹfa yii, pe fidio kan to ṣafihan iwa palapala ti Portable hu ni agbegbe kan nipinlẹ Ogun ti de ọdọ awọn, tori ẹ lawọn ṣe n wa a.
Ninu fidio naa, wọn ni Portable paṣẹ fawọn bọisi ẹ pe ki wọn ba oun fiya jẹ ọkunrin kan to ṣẹ oun, lawọn yẹn ba bẹrẹ si i din dundu iya fonitọhun, wọn si ṣe e leṣe gidi.
Oyeyẹmi ni o ya awọn lẹnu pe iru iwa ta-ni-yoo-mu-mi ati fifọwọ pa ida ofin loju bẹẹ le waye latọdọ gbajugbaja olorin to yẹ awo-fi-ṣapẹẹrẹ fawọn ọdọ atawọn ọmọde. Wọn lawọn o ni i gba iru aṣakaṣa bẹẹ laaye nipinlẹ Ogun, tori ẹ lawọn ṣe fẹẹ wadii fidio naa, ki wọn si fidi ododo mulẹ.
“A n lo anfaani yii, lati gba Okikiọla Habeeb, ti inagijẹ rẹ n jẹ Portable lamọran pe ko ṣafihan ara ẹ ni teṣan ọlọpaa to ba sun mọ ọn ju lọ ni ipinlẹ Ogun, tabi ko wa si olu-ileeṣẹ wa l’Abẹokuta.
To ba kuna lati ṣe bẹẹ laipẹ, a maa kede pe kawọn agbofinro mu un nibikibi to ba wa, gẹgẹ bii afurasi ọdaran.
Iru iwa ṣiṣedajọ lọwọ ara ẹni bii eyi ta a ri ninu fidio yii ki i ṣe iwa to yẹ lawujọ, ko si ba iwa ọmọluabi kankan mu, o tako ofin ilẹ wa patapata. O jẹ aṣa to le fẹsẹ awọn ọdọ mi-in le ọna iwa abeṣe lawujọ.
Tori ẹ, ofin o mọ ipo tabi aaye tẹnikẹni le wa, ẹni ba fọwọ pa ida ofin loju, ofin yoo pa iru wọn lọwọ gbẹrẹgẹdẹ bii abẹfẹlẹ ni.”
Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: