Awọn ọlọpaa run ọkada rẹpẹtẹ ti wọn rufin irinna jegejege l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Alọ lamilami, bii abẹrẹ to bọ sinu okun, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe ọrọ awọn ọkada to din diẹ lẹẹẹdẹgbẹta ti wọn gba nidii awọn to rufin irinna ọkọ nipinlẹ naa, niṣe ni wọn run wọn jegejege, ti wọn si sọ wọn di okiti awoku ọkada ti wọn maa ko danu.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Hakeem Odumosu, ni eto rirun awọn ọkada tọwọ ba naa womuwomu ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti pẹ tawọn ti maa n ṣe e, o kan jẹ kọrọ lawọn ti maa n ṣe e tẹlẹ ni, awọn ki i jẹ kawọn eeyan ri i bii tasiko yii.

O ni idi tawọn fi ya fọto ati fidio bi wọn ṣe n run awọn ọkada naa jegejege, eyi to waye nile ijọba Eko, l’Alausa, Ikẹja, sode, jẹ lati fopin si irọ ati ahesọ tawọn eeyan kan n sọ kiri pe niṣe lawọn n dọgbọn ta awọn ọkada tọwọ ba naa labẹnu, tabi ti wọn n paarọ ẹya ara ẹ si omi-in. Ẹrọ katapila gagara kan ni wọn n lo lati fi wo awọn ọkada naa womuwomu, ti yoo si sọ wọn di ẹyọ ẹyọ bii agbado ti wọn yin kuro lara ṣuku.

O lawọn tun fẹ ko han sawọn ti wọn ṣi n fi ọkada rufin irinna l’Ekoo pe ori ọka ni wọn fi n họmu, adanu nla ni yoo ja si fun wọn tọwọ ba fi tẹ awọn ati ọkada wọn.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Satide yii nipa iṣẹlẹ naa, Odumosu ni awọn o ni i jawọ ninu mimu ofin ijọba ṣẹ, awọn araalu ni ki wọn lọọ pinnu lati ma ṣe tasẹ agẹrẹ sofin.

Leave a Reply