Awọn ọlọpaa sa kabakaba nigba tawọn ṣọja ya bo tesan wọn l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Tibọn-tibọn lawọn ọlọpaa tesan to wa lagbegbe Ọbẹlawọ, niluu Oṣogbo, fi sa wọnu agboole lasiko ti awọn ṣọja ya bo wọn lati tu ọkan lara wọn ti wọn ti mọle silẹ.

Aago mẹjọ alẹ ọjọ lṣẹgun, Tusidee, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ko si sẹni to mọ ẹṣẹ ti ṣọja tawọn ọlọpaa naa ti mọle ṣẹ wọn, ṣugbọn okete ọrọ naa pada boru mọ wọn lọwọ tori alediju lawọn ṣoja le wọn.

Awọn to n gbe lagbegbe naa ṣalaye pe koboko lawọn ṣọja ti wọn to marun-un ọhun kọkọ yọ ti awọn ọlọpaa nigba ti wọn debẹ, ko too di pe awọn n gbọ iro ibọn lakọlakọ, tawọn ko si mọ boya awọn ọlọpaa lo n yinbọn tabi awọn ṣọja.

Wọn fidi rẹ mulẹ pe ko si ibọn kankan lọwọ awọn ṣọja naa, ṣugbọn ọbẹ pẹlẹbẹ ti wọn maa n fi sapo wa lara wọn, ati pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ọlọpaa ni wọn n yinbọn naa lasiko ti wọn n sa lọ.

Iwadii akọroyin wa fi han pe ọsan ọjọ Tusidee ni sọja ti wọn ti mọle naa lọ si tesan ọhun lati gba beeli afurasi kan ti wọn mu nibẹ, ṣugbọn a ko mọ bi ọrọ ṣe waa di eyi ti wọn ti ṣọja naa mọle si.

Ṣugbọn ninu alaye tirẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn janduku ni wọn ya bo tesan naa lati tu ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun tọwọ tẹ ni Ẹgbatẹdo, l’Oṣogbo, silẹ.

Lasiko naa, Ọpalọla sọ pe awọn janduku naa tu Sanni Adeṣẹgun silẹ lahaamọ ọlọpaa, ṣugbọn ọwọ pada tẹ awọn afurasi mẹta miiran.

Leave a Reply