Awọn ọlọpaa SARS le awọn ọmọ Yahoo pa l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii jọ, inu ibẹrubojo lawọn  eeyan agbegbe Oke-fia, niluu Oṣogbo, wa pẹlu bi awọn ọdọ ti wọn to aadọta ṣe ya bo oju titi, ti wọn si ni afi dandan kawọn gbẹsan iwa ika ti wọn sọ pe awọn ọlọpaa SARS hu.

Ni nnkan bii aago mefa irọlẹ ọjọ lṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wahala naa bẹrẹ, ohun ti a gbọ ni pe awọn ọdọkunrin mẹrin kan tawọn eeyan fura si bii ọmọ Yahoo lọ si ile itaja igbalode Ọṣun Mall, to wa lagbegbe Ọlaiya, lati lọọ ra nnkan.

Bi wọn ṣe ra nnkan tan ni wọn wọnu mọto Toyota Corolla to ni nọmba KUJ 553 LY ti wọn si fori le ọna Adesọji Aderẹmi East-West by-pass, ṣugbọn ṣe lawọn ọlọpaa SARS ti wọn wa ninu mọto pupa ti wọn kọ JTF si lara tẹle wọn.

Bi awọn ọmọ yii ṣe ri i pe awọn SARS n le awọn naa ni wọn tubọ n sare lọ. Lojiji la gbọ pe mọto wọn la ori mọ opo-ina onisimẹnti, to si lọ jin sinu ọgbun kan to wa lagbegbe ibẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe oju-ẹsẹ ni ọmọkunrin to wa mọto naa ku, bẹẹ lawọn ọlọpaa SARS naa si sa lọ. Koda, a gbọ pe meji lara awọn ọmọ yii ti wọn farapa yannayanna tun ti gbẹmi mi loju-ọna ọsibitu.

Inu bi awọn ọdọ ti wọn ri iṣẹlẹ naa, wọn gbe oku eyi to wa mọto lọ sẹnu ọna ile ijọba l’Oke-fia, alubami ni wọn si na awọn ọlọpaa ti wọn n dari ọkọ lorita Oke-Fia.

Wọn dana si awọn oju-ọna, wọn ko jẹ ki mọto kankan kọja, wọn sọ pe afi ti awọn ba dana sun ọkọ JTF mi-in ti wọn ba l’Oke-fia, afigba ti awọn ọlọpaa lọọ tunra mu, ti wọn si ya bo wọn ni wọn too tuka.

Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Ọṣun lori eto aabo, Arabinrin Abiọdun Ige, sọ pe oun ko ti i ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa ohun to ṣẹlẹ naa.

Leave a Reply