Awọn ọlọpaa ti fun Baba Ijẹṣa ni beeli

Jide Alabi

Ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Lanre Omiyinka, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, to ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa lati bii ọsẹ mẹta sẹyin ti gba ominira bayii pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe fun un ni beeli ni ọjọ Aje, Mọnde, ọṣe yii.

Agbẹjọro rẹ, Adeṣina Ogunlana, lo sọ eleyii di mimọ. O ni ni nnkan bii wakati kan sẹyin ni wọn gba beeli rẹ. Ṣugbọn awọn ti n mura bayii lati fọwọ si gbogbo iwe to yẹ lori beeli naa ki ọkunrin naa le maa lọ sile.

Nitori ilera rẹ ti wọn ni ko ṣe daadaa ni wọn ni wọn ṣe ni wọn da a silẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lopin ọsẹ to kọja ni lọọya ọkunrin naa pariwo pe ọkunrin naa ko gbadun mọ, ko le rin daadaa, bẹẹ ni o ti ru hangogo.

Leave a Reply