Awọn ọlọpaa ti ju Sẹnetọ Rochas Okorocha, gomina  ipinlẹ Imo tẹlẹ, satimọle

Faith Adebọla

Gomina to ṣẹṣẹ kuro lori aleefa nipinlẹ Imo, to tun jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, Sẹnetọ Rochas Okorocha, ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn lawọn mu ọkunrin naa lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde yii, latari bi wọn ṣe fẹsun kan an pe o ko awọn janduku kan atawọn ololufẹ rẹ sodi, wọn si lọọ ṣakọlu si otẹẹli kan ti wọn pe ni Royal Palm Estate, eyi tijọba ipinlẹ Imo faṣẹ ọba ti pa l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii.
Gomina tẹlẹri naa ti kọkọ sọ pe ikọja-aaye ni fun ijọba to wa lori aleefa lati faṣẹ ọba ti otẹẹli to jẹ tiyawo oun, lai si ẹri tabi ẹsun kan nile-ẹjọ lodi si Abilekọ Okorocha lori ilẹ ati ile to kọ naa.
A gbọ pe nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Aiku yii, tibinu tibinu ni Sẹnetọ Okorocha atawọn isọngbe rẹ lọọ ja gbogbo agadagodo ati okun ti wọn so mọ ẹnu geeti otẹẹli naa danu.
Wọn niṣẹlẹ yii mu kawọn janduku ba awọn ọkọ ayọkẹlẹ kan jẹ, ti wọn si ṣe awọn agbofinro kan atawọn to fẹẹ gbẹja aṣẹ gomina naa leṣe.
Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe wi, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ni wọn ti mu Okorocha atawọn janduku kan tọwọ ba sakata awọn ọlọpaa ipinlẹ Imo bayii, ati pe wọn yoo foju gbogbo wọn bale-ẹjọ lowurọ ọjọ Aje, fun ẹsun idaluru, didi alaafia ilu lọwọ, ati titapa si aṣẹ ijọba.

Leave a Reply