Awọn ọlọpaa ti mu Ṣukura, lẹyin to pa ọmọ oṣu kan to bi lo ju oku ẹ sodo Ogun l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta                      

 Ṣukurat Ọlajọkẹ lẹ n wo yii, ẹni ọdun marundinlogoji (35) to ti bimọ mẹfa tẹlẹ ni. Ọmọ keje lo gbe oku ẹ dani yii, oun naa lo si pa ọmọ oṣu kan naa to ju oku ẹ sodo Ogun, l’Abẹokuta!

Ni nnkan bii aago mẹjọ ààbọ̀ alẹ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn ọlọpaa to n ṣọ agbegbe Ẹnugada, l’Abẹokuta, ri obinrin kan to n ju nnkan kan nu sodo Ogun. Bo ti ju kinni ọhun sodo tan ko kuro nibẹ, iṣesi rẹ lo fu awọn ọlọpaa naa lara ti wọn fi lọọ ba a nibi to duro si.

SP Baba Hamzat atawọn ikọ ọlọpaa yooku fọrọ wa obinrin yii lẹnu wo, o si jẹwọ fun wọn pe ọmọ ikoko toun bi loṣu to kọja loun waa ju oku ẹ sodo Ogun, nitori ẹni to fun oun loyun ọmọ naa ko gba a, bẹẹ ni ko fẹ oun gẹgẹ bii aya.

Ṣukura ṣalaye fawọn ọlọpaa pe funra oun loun pa ọmọ ikoko naa, nigba toun ro gbogbo ẹ pọ, toun ko ri i ro loun ṣe pa a, toun si waa ju oku ẹ somi lalẹ.

O fi kun alaye ẹ pe agboole Alakoye, ni Igbo-Ọra, nipinlẹ Ọyọ, loun ti wa. O ni nigba ti ko si agbara foun lati tọju ọmọ keje toun bi yii loun ṣe pa a, toun si waa ju u sodo Ogun, l’Abẹokuta.

Iwadii awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe ọkunrin mẹta ọtọọtọ ni Ṣukura bi awọn ọmọ mẹfa to kọkọ bi fun, ko si si nile ẹnikẹni ninu wọn gẹgẹ bii iyawo.

Ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Hakeem ni wọn lo loyun ọmọ to pa yii fun, nigba tiyẹn ko si gba oyun debi ti yoo gba ọmọ lo jẹ ki Ṣukura sọ ara ẹ di apaayan, to pa ọmọ to ru oyun ẹ foṣu mẹsan-an, to ranju ko too bi i.

Ẹka awọn apaayan ni ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, paṣẹ pe ki wọn gbe Ṣukura lọ, o si ti wa nibẹ bayii to n ṣalaye ara ẹ.

Leave a Reply