Awọn ọlọpaa ti mu Ahmed ati Ṣẹyẹ, wọn lawọn ni wọn pa Gafaru l’Abẹokuta

Kazeem Aderohunmu

 

Awọn ọlọpaa ti mu Ahmed ati Ṣẹyẹ, wọn lawọn ni wọn pa Gafaru l’Abẹokut

Olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ti sọ pe ile-ẹjọ lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji yii; Ahmed Hamzat ẹni tawọn eeyan tun mọ si Elemure ati Kuyoro Ṣẹyẹ, yoo ti lọọ ṣalaye ẹnu wọn daadaa lori ẹsun ti wọn fi kan wọn pe awọn ni wọn pa Gafaru Ṣobiye.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, ni iṣẹlẹ ọhun waye laduugbo Ijẹmọ-Agbadu, niluu Abẹokuta. Awọn janduku ọmọ ẹgbẹ okunkun ti Ahmed Elemure n dari, iyẹn Aye ni wọn sọ pe wọn lọọ ka Gafaru Ṣobiye mọle, ti wọn si sun mọ ọn daadaa ki wọn too yinbọn lu u.

Loju-ẹsẹ ni wọn sọ pe awọn araadugbo ti sare si Gafaru, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, nitori ọsibitu ti wọn ti lọọ fun un ni itọju naa lo ku si.

Ninu iwadii awọn ọlọpaa lọwọ ti tẹ awọn ọkunrin mejeeji yii, Ahmed Hamzat ati Ṣẹyẹ, bẹẹ ni wọn sọ pe wọn yoo foju bale-ẹjọ laipẹ.

Ṣa o, ALAROYE fọrọ wa awọn ẹni-afurasi ọhun lẹnu wo, alaye ti Hamzat Ahmed ṣe ni pe oun kọ loun pa ọmọkunrin naa, bo tilẹ je pe oun ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ri. Hamzat fi kun ọrọ ẹ pe oun ti jawọ tipẹ, ati pe awọn to mọ oun mọ iru iwa bẹẹ laduugbo ni wọn tọka oun, ti awọn ọlọpaa fi sọ pe oun mọ nipa iṣelẹ naa.

Pẹlu omi loju lo fi n sọ pe oun ko mọ Gafaru to ti doku yii ri. Ṣẹyẹ ni tiẹ jẹwo pe loootọ loun n ṣẹgbẹ okunkun Ẹyẹ, ṣugbon oun ko lọwo ninu iku ọkunrin ti wọn sọ pe wọn pa yii.

O ni, “Awọn to maa n ri mi pẹlu awọn ẹgbọn kan laduugbo ni wọn tọka mi, ẹmi ko si ninu awọn to pa Gafaru.

Ile-ẹjọ ti sọ pe niwaju Adajọ ni awọn mejeeji yoo ti sọ bọrọ ọhun ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply