Awọn ọlọpaa ti mu awakọ ajagbe to pa eeyan meji l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Titi di asiko ta a pari akojọpọ iroyin yii ni dẹrẹba to wa ọkọ ajagbe to pa awọn meji kan loju ọna Poli, niluu Ado-Ekiti, ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa, ti wọn n ba iwadii lọ.

Laaarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, to jẹ ayajọ ọjọọbi Anọbi Muhammed niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si awọn oloogbe meji ọhun lasiko ti wọn fẹẹ gba ẹgbẹ ọkọ ajagbe to gbe epo naa pẹlu ọkada.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan naa gbe apo agbado dani lori ọkada, bi wọn si ṣe fẹẹ ya tirela naa silẹ ni wọn fi ẹgbẹ kọ ọ, ibẹ ni ọkọ ọhun si ti tẹ wọn pa nigba ti wọn ko sabẹ ẹ.

Ariwo ijamba naa lawọn eeyan agbegbe ọhun gbọ ti wọn fi sare jade, ṣugbọn ko si nnkan ti wọn le ṣe nitori loju-ẹsẹ lawọn eeyan naa ti dagbere faye.

Iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ nla fawọn to ri oku awọn mejeeji pẹlu bi ọpọlọ wọn ṣe fọ, ti ẹran ara wọn si ja jalajala sori titi nibẹ.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ sọ pe awọn ọlọpaa teṣan Odo-Ado lo sare debẹ lati gba tirela ọhun silẹ lọwọ awọn to fẹẹ jo o, ti wọn si mu dẹrẹba naa, bẹẹ lawọn panapana palẹ oku awọn oloogbe mọ.

Ninu alaye ti Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, ṣe fun wa lori iṣẹlẹ naa, o ni loootọ lawọn eeyan naa fara kọ ọkọ ajagbe ọhun ki wọn too ko sabẹ ẹ.

O waa sọ ọ di mimọ pe awọn ti yọnda awọn oku naa fun mọlẹbi wọn ki wọn le lọọ sin wọn gẹgẹ bi ẹbẹ ti wọn bẹ ileeṣẹ ọlọpaa.

Leave a Reply