Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin nnkan bíi oṣù meji tawọn amookunṣika pa àgbẹ aládàá nla kan lagbegbe Ibarapa, Ọmọwe Fatai Aborode, ọwọ àwọn agbofinro ti tẹ àwọn ọdaju eeyan to ran ọmọwe naa lọ sọrun apapandodo.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kọkànlá, oṣù kejìlá, ọdún 2020, láwọn ẹruuku lọọ ka Aborode, to jẹ aláṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Kunfayakun Green Treasures Limited mọnu oko ẹ to wa lọna Apodun, niluu Igangan, ti wọn sì pa a.
Ọkunrin tí wọn pa nipakupa yii lawọn ara agbegbe Ibarapa n wo gẹgẹ bíi olùrànlọwọ wọn nítorí bo ṣe pèsè iṣẹ fún ẹgbaagbeje eeyan pẹlu bo ṣe gba ọpọ eeyan sínu oko nla to dá sílùú Igangan gẹgẹ bíi oṣiṣẹ.
ALAROYE gbọ pe o ti to bíi ọjọ mélòó kan sẹyin tawọn agbofinro ti ri awọn afurasi apaayan tó ràn bàbá olowo ilu Igangan naa lọ sọrun ọsan gangan mu.
Nigba to n fìdí iroyin yii múlẹ fawọn oniroyin n’Ibadan lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, to kọja, gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde fi aidunnu ẹ hàn sí ọwọ yẹpẹrẹ ti awọn ọlọpaa fi mú iwadii wọn lori iṣẹlẹ ipaniyan ọ̀hún.
O ni ọrọ to le ṣi awọn araalu lọna lawọn ọlọpaa n gbe jade lori iṣẹlẹ yii pẹlu bi wọn ṣe n purọ pe àwọn Fulani darandaran ni wọn pa a nigba to jẹ pe iku ọmọwe naa lọ́wọ́ oṣelu ninu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ariwo ti gbogbo eeyan n pa ni pe awọn Fúlàní ló pa Dokita Aborode. Ṣugbọn nigba ti mo ṣabẹwo sí Ibarapa, mo lọ sile baba ẹ, wọn sì jẹ kí n mọ pe iku Dokita lọwọ oṣelu ninu.
“Wọn ni aiṣiṣẹ bíi iṣẹ awọn ọlọpaa naa wa lara ohun to ṣokunfa iku Dokita Aborode.
“Wọn ní ẹnikan lo fi ọkada gbe e lọ soko lọjọ yẹn. Bi wọn ṣe n ti inu oko bọ láwọn eeyan yẹn da wọn duro, ti wọn sì já Dokita Abodore silẹ lẹyin ọkada to gbe e.
“Ẹni tó fọkada gbe é sáré kegbajare lọ sile fún iranlọwọ àwọn èèyàn.
“Awọn kan naa ti wọn n ti inu oko wọn bọ ba wọn níbẹ, wọn sì gbọ bi Dokita ṣe n bẹ awọn to fẹẹ pa a ati itakurọsọ to waye laarin wọn. Mo ni ede wo lawọn to pa a n sọ, wọn láwọn àgbẹ̀ to gbọ ọrọ tí wọn n sọ lọjọ yẹn so pe Yoruba ni wọn n sọ.
“Mo sún niluu Igangan di ọjọ kejì ni. Nigba ti mo dé Ibadan pada, mo ṣalaye ohun ti mo gbọ nípa ikú Dokita Aborode fawọn agbofinro. Mo ni njẹ ẹ ti gbọ nnkan ti mo gbọ yii, wọn ni bẹẹ ni, awọn ti ṣewadii lẹnu ọpọ èèyàn. Mo ni ki lẹ waa ti ṣe sí í, n ni wọn ba n wo mi loju, wọn kò le sọrọ.
“Mo wáa pe ọga ọlọpaa (CP Ngozi Onadeko) pe wọn gbọdọ mu àwọn afurasi ọdaran wọnyi ki wọn sí fọrọ wa wọn lẹnu wo.