Awọn ọlọpaa ti mu dẹrẹba ti wọn lo fẹẹ ta ero ọkọ rẹ fawọn ajinigbe l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ awakọ bọọsi kan ti wọn ṣafihan rẹ ninu fidio kan pe o ta awọn ero ọkọ rẹ fun awọn ajinigbe ni agbegbe Itaure si Ẹfọn-Alaaye, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bi iwe kan lati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, eyi ti alukoro wọn fọwọ si, ti wọn fi ṣọwọ sawọn akọroyin nipinlẹ naa ṣe sọ, ni deede aago mejila ku iṣẹju mẹẹẹdogun, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje yii, ni ijamba ọkọ kan ṣẹlẹ niluu Ẹfọn-Alaaye.

O ṣalaye pe awọn ero ọkọ yii gbera lati ilu Ado-Ekiti, wọn n lọ si ilu Ibadan fun ayẹyẹ ọdun Ileya.

Bi awakọ bọọsi yii ṣe de ojuko ibi ti ijamba ọkọ yii ti waye ni dẹrẹba yii duro, ti awọn ero ọkọ rẹ ti ko din ni mejidinlogun si bọ silẹ lati inu ọkọ lati doola ẹmi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si.

Awọn agbofinro ni bi awakọ yii ṣe duro diẹ lo gbe ọkọ rẹ ati ẹru awọn ero naa, to si fi wọn silẹ sibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ.

A gbọ pe niṣe lawọn ero yii fẹsẹ rin ọpolọpọ ibusọ laarin inu igbo, eyi to mu ki ẹmi wọn wa ninu ewu laarin aginju igbo naa.

Lẹyin wakati diẹ ni wọn too jade si gbangba lati inu igbo ti wọn ti n rin bọ, ti wọn si lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa to wa ni Ẹfọn-Alaaye leti.

Lọgan la gbọ pe awọn agbofinro bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ni dereba mọto ọhun ti de ilu Ileṣa. Awọn ọlọpaa ilu Ijamọ, nipinlẹ Ọṣun, ni wọn fi panpẹ ofin gbe e, ti wọn si da a pada si Ẹfọn-Alaaye, nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni fidio iṣẹlẹ naa gba ori ẹrọ ayelujara kan, pe awọn awakọ kan lati ilu Ado-Ekiti ta awọn ero inu ọkọ wọn fun awọn ajinigbe loju ọna to lọ lati Ade-Ekiti si Oṣogbo.

Ṣugbọn ninu alaye ti awọn agbofinro ṣe nipasẹ Alukoro wọn, Ọgbeni Sunday Abutu, o ni iṣẹlẹ naa ko ri bi awọn eeyan ṣe ro o. O ni awọn ọta ilọsiwaju kan lo wa nidii fidio yii.

Bẹẹ lo ni awọn ti gba ọrọ silẹ lẹnu awọn ero ọkọ yii lati ṣe iwadii to yẹ nipa iṣẹlẹ naa.

Alukoro yii sọ pe ọkọ bọọsi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ KOGI KPA 116 LG ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti.

Leave a Reply