Awọn ọlọpaa ti mu Joseph to yin iyawo ẹ lọrun pa sinu ile l’Abuja

Ọwọ ọlọpaa olu ilu ilẹ wa niluu Abuja ti tẹ ọmọkunrin kan, Joseph Mbounu Ifeanyi, to yin iyawo rẹ, Evelyn Ọmape Alifia Yakubu, ti wọn n gbe ni adugbo Lugbe, niluu Abuja lọrun pa, to si tun ṣa a ṣakaṣaka.

Ohun to ṣe awọn eeyan ni kayeefi ni pe ko ti i ju oṣu meji pere lọ ti awọn mejeeji ṣegbeyawo.

ALAROYE gbọ pe o ti to ọjọ mẹta ti ede aiyede ti n waye laarin awọn tọkọ-tiyawo yii, ti ọkọ rẹ to n ṣiṣẹ awọn to n ba wọn tun ina ṣe (Elettrical Technician) naa si ti n halẹ mọ iyawo to ṣẹṣẹ fẹ yii pe oun maa pa a. Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun yii, ni wọn ni ọmọbinrin naa ri ibọn lọwọ ọkọ rẹ. Lasiko to n gbero lati fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ni wọn ni ọkunrin naa yin in lọrun, to si tun ṣa a ni gbogbo ara. O ba oku naa jẹ debii pe awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa ko le duro de iwadii ọlọpaa ti wọn fi lọọ sin in.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa Abuja yii, Josephine Adeh, ṣalaye pe ọkunrin kan, Aduojo Danile Yakubu, lo mu ẹsun lọ si ẹka teṣan ọlọpaa Trademore, pe wọn pa ọmọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Evelyn, ati pe wọn ko si gburoo ọkọ rẹ latigba tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Iwadii awọn agbofinro fi han pe Ifeanyi to jẹ ọkọ obinrin yii ni wọn ri gbẹyin pẹlu rẹ, oun naa lo si pe awọn mọlẹbi iyawo rẹ lati sọ fun wọn pe o ti ku, ṣugbọn wọn ko mọ ibi ti oun gan-an wọlẹ si.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ni awọn ọlọpaa tẹle awọn mọlẹbi lọ si ile awọn tọkọ-tiyawo naa. Iyalẹnu lo jẹ fun wọn pe niṣe ni ọkọ obinrin yii yin in lọrun pa, to si tun fada ṣe ara rẹ ṣakaṣaka.

Awọn ọlọpaa fẹẹ gbe oku naa lọ si mọṣuari ki wọn le bẹrẹ iwadii lori rẹ, ṣgbọn ipo ti awọn mọlẹbi ba oku ọmọ wọn yii ko tẹ wọn lọrun rara, eyi lo fa a ti wọn fi ni awọn yoo lọọ si in loju-ẹsẹ ni, dipo mọṣuari ti wọn ni ki wọn gbe e lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ilu Abuja, Babaji Sunday, ti ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati ri i pe iwadii ijinlẹ waye lori iku to pa ọmọbinrin naa.

Leave a Reply