Awọn ọlọpaa ti mu tẹgbọn-taburo to ji baba wọn gbe, ti wọn n beere owo itusilẹ

Iya ati baba kan naa lo bi awọn ọkunrin meji yii, ni Yola, nipinlẹ Adamawa. Ṣugbọn niṣe lawọn mejeeji ti wọn jẹ tẹgbọn-taburo yii gbimọ-pọ, ti wọn ji baba to bi wọn gbe, wọn si ti n beere owo itusilẹ paapaa, ko too di pe ọwọ palaba wọn segi.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe lẹyin ti awọn gende meji yii ji baba wọn gbe tan, wọn tọju rẹ sibi ti ẹnikẹni ko ti ni i fura. Lẹyin igba naa ni wọn si waa n beere owo rẹpẹtẹ lọwọ awọn ẹgbọn ati aburo baba naa, wọn ni bi wọn ko ba mu owo wa, ki wọn gbagbe pe wọn yoo tun foju kan eeyan wọn naa mọ o.

Ṣugbọn awọn ẹbi baba wọn ko ri owo tawọn ajinigbe naa n beere san, ko si jọ pe kinni kan wa ti wọn le ṣe si i rara.

Nigba tawọn mejeeji yii ko ri owo gba, ti wọn ko si fẹ ki aṣiri tu pe awọn lawọn ji baba awọn gbe, wọn pinnu lati kuku pa a danu, ki ohun to n run nilẹ tan kia.

Afi ti pe awodi oke wọn ko mọ pe ara ilẹ n wo oun, awọn ọmọ to ji baba gbe yii ko mọ pe ẹni kan ri awọn lasiko ti wọn n gídì baba naa mọlẹ, ti wọn fipa wọ ọ sinu ọkọ ti wọn fi gbe e lọ.

Ẹni naa lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ẹbi baba naa to n daamu lati san owo itusilẹ rẹ, bi wọn ṣe lọọ fọlọpaa gbe awọn ọmọ yii niyẹn.

Awọn mejeeji ti wa latimọle bayii, ko le pẹ ti wọn yoo fi de kootu, lati dahun ẹsun ijinigbe.

Leave a Reply