Awọn ọlọpaa ti mu un o: Emmanuel to n fi igbẹ jẹ burẹdi nIbadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bi ko je awọn ọlọpaa ti wọn tete debẹ ni, afaimọ lawọn ara adugbo ko ni lu ọkunrin Ibo kan ti wọn n pe ni Emmanuel Egbu pa niluu Ibadan lanaa yii. Wọn ba a to n fi igbẹ awọn ọmọ keekeekee jẹ burẹdi ninu ọja Sanngo ni. Bẹẹ ni ki i ṣe pe ara rẹ ko ya, nnkan kan ko ṣe e, ni wọn ṣe fura si i pe oogun owo lo fẹẹ fi kinni naa ṣe.

Egbu yii lọpọ eeyan mọ bii ẹni mowo gẹgẹ bii oniṣowo ipara atawọn nnkan ìṣaralóge obinrin bii wiigi ati ṣampu. Bii igba ti awọn alaisan ba n lọ sọdọ dokita fun itọju lawọn eeyan maa n lọ sọdọ ẹ fun imọran lori iru ipara to yẹ ki wọn lo, to si maa n sọ eyi to maa ba ẹnikọọkan wọn lara mu fun.

Ṣugbọn ko sẹni to mọgba ti ọkunnrin yii dọgbọn ṣa awọn igbọnsẹ ti awọn ọmọ keekeeke ti wọn jẹ awọn ọmọ oniṣowo ẹgbẹ ẹ ya ninu ọra ti awọn iya wọn ko won si, afi nigḅa to bẹrẹ si i fi kinni naa jẹ burẹdi ninu ọja Sango nibẹ ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ana yii (ọjọ Abamẹta, Satide).

Ẹnikan to lọọ raja ni Sango lasiko iṣẹlẹ yii ṣalaye fakọroyin wa pe ọkan ninu awọn ontaja ẹgbẹ ẹ lo ka a mọ, ti Egbu si bẹ onitọhun pe oun yoo fun un ni miliọnu meji Naira bo ba le bo oun laṣiiri ti ko sọrọ naa fẹnikan.

Ṣugbọn onitọhun ko gba, bi iyẹn si ṣe figbe ta lawọn eeyan ti pe le wọn lori. Ọpọ ninu awọn onibaara rẹ paapaa to gbọ agbọsọgbanu iroyin yii ni wọn sare lọ sibẹ lọọ foju lounjẹ.

Awọn to mọ nipa iru nnkan bẹẹ sọ pe oogun owo lọkunrin Ibo yii fi kinni ọhun ṣe. Idi ree tawọn eeyan ṣe mura lati ko apola igi bo o ko le jẹwọ ohun to fẹẹ fi ẹgbin to ti inu  ara awọn ọmọọlọmọ jade ṣe. Ṣugbọn awọn agbofinro to tete debẹ ko gba fun wọn lati ṣe bẹẹ, ṣe teṣan ọlọpaa Sango ko jinna sibẹ rara.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa Sango ni wọn mu Egbu lọ si teṣan wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn eeyan ka a mọbi to ti n palẹ awọn igbọnsẹ mọ nibikan ninu ọja. Wọn fa a le awọn ọlọpaa teṣan Sango lọwọ. Nibẹ lo maa gba de CID, ni Iyaganku, iyẹn ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ.”

Leave a Reply