Awọn ọlọpaa ti mu Yusuf, ọmọ ẹ lo fẹẹ ta lowo pọọku

Adewale Adeoye

Baale ile kan, Ọgbẹni Yusuf Umar, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta to fẹẹ ta ọmọ bibi inu rẹ ti ko ju ọdun marun-un lọ lowo pọọku lọwọ awọn ọlọpaa agbegbe Warji, nipinlẹ Bauchi, ti tẹ bayii, to si ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni afunrasi ọdaran ọhun lọọ ba iya ọmọ naa ti wọn ko jọ gbe papọ mọ nile rẹ, o loun fẹẹ mu ọmọ ọhun lọ sọdọ ẹgbọn oun kan to n gbe nitosi ibi ti wọn n gbe. Loju-ẹsẹ ni iya ọmọ ti yọnda ọmọ ọhun fun un. Ṣugbọn kaka ki Yusuf mu ọmọ rẹ lọ sibi to sọ funyawo ẹ pe oun fẹẹ mu un lọ, ọdọ ẹni to fẹẹ ra ọmọ yii lowo pọọku lọwọ rẹ lo mu un lọ. Ibi ti wọn ti n dunaa-dura lori iye ti yoo gba lori ọmọ yii ni ẹni to dibọn bii ẹni to fẹẹ ra ọmọ ti yọ kaadi idanimọ rẹ sita pe ọlọpaa loun, lo ba fọwọ ofin mu Yusuf lọ sagọọ ọlọpaa agbegbe naa.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ naa, C.P Auwal Musa Muhammad, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Warji, nipinlẹ Bauchi, ni afurasi ọdaran ọhun, o lọọ ba iyawo rẹ ti i ṣe iya ọmọ ọhun nile to n gbe, ohun to sọ fun un ni pe oun fẹẹ mu ọmọ naa lọ sọdọ ẹgbọn oun kan to n gbe nipinlẹ Bauchi yii kan naa.  Iya ọmọ ko si ko ja a niyan rara, o jọwọ ọmọ rẹ ti i ṣe ọmọ ọdun marun-un silẹ fun baba rẹ yii. Yusuf mu ọmọ rẹ lọ sibi to ti fẹẹ ta a, ni miliọnu kan aabọ Naira, ẹnu ọrọ yii ni wọn wa ti ẹni to fẹẹ ra ọmọ naa lọwọ rẹ fi yọ kaadi idanimọ rẹ sita pe ọlọpaa loun, lo ba fọwọ ofin mu Yusuf ju sahaamọ  lẹsẹkẹsẹ.

Ọga ọlọpaa ni iwadii n lọ lọwọ nipa iṣẹlẹ naa, tawọn si maa too foju Yusuf  bale-ẹjọ.

Leave a Reply