Awọn ọlọpaa ti sọrọ lori rogbodiyan Atan-Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti sọrọ lori rogbodiyan to ṣẹlẹ ni teṣan ọlọpaa Atan-Ọta laaarọ Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti ni DPO teṣan naa dagbere faye.

Oyeyẹmi ṣalaye pe DCO teṣan naa, DSP Augustine Ogbeche, lawọn to fa rogbodiyan naa pa. O fi kun un pe bakan naa ni wọn tun ṣe DPO teṣan yii kan naa leṣe, koda o lawọn ko mọ ibi ti DPO naa torukọ ẹ n jẹ Sikiru Olugbenga, wa bayii.

O tẹsiwaju pe araalu kan naa ku ninu rogbodiyan ọhun. Alukoro sọ pe yatọ si gbogbo eyi, awọn eeyan naa tun ji awọn dukia olowo iyebiye lọ ni teṣan ọlọpaa naa.

Lọjọ Iṣẹgun yii kan naa lo ni awọn ọmọkunrin kan kọ lu teṣan ọlọpaa Ọbada-Oko, l’Abẹokuta, kan naa, wọn si ba ibẹ jẹ. Ati ẹ gbọ pe niṣe ni DPO ibẹ fikunlẹ bẹ ẹ fawọn bọisi naa, ohun ti ko jẹ ki wọn dana sun ibẹ niyẹn.

Oyeyẹmi waa sọ pe o yẹ kawọn ọdọ ranti pe latigba ti ọrọ SARS yii ti bẹrẹ, ọlọpaa ko fa wahala, kódà pẹlu bawọn kan ṣe ba teṣan awọn jẹ. O ni gbogbo eeyan merindinlogoji (36) tọwọ ba lasiko rogbodiyan akọkọ lawọn ti fi silẹ, fun idi eyi, o ni kawọn ọdọ yee wahala awọn, ọlọpaa ki i ṣe onijagidijagan.

Bakan naa lo ni kawọn obi ati olori ilu kilọ fawọn eeyan wọn.

 

Leave a Reply