Awọn ọlọpaa ti tu aṣiri awọn to waa jo ile Sunday Igboho

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọrọ lori ijamba ina to waye laaarọ ọkọ Iṣẹgun, Tusidee yii, n’Ibadan, nile Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, wọn ni awọn janduku kan ni wọn ṣiṣẹ buruku ọhun loru, mọto meji kan ni wọn gbe wa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Gbenga Fadeyi, fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, o ni ọkọ Hummer ati Micra ni wọn gun wa ni nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju diẹ loru, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn soke, ki wọn too sọna sile naa, ti wọn si ba tiwọn lọ.

Gbenga ni gbara ti DPO Sanyo ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii lo ti sare tẹ ileeṣẹ panapana laago, oju ẹsẹ loun funra ẹ si ti lọ sibi iṣẹlẹ naa pẹlu awọn ọlọpaa meloo kan.

O lawọn panapana tete pa ina naa, yara igbalejo to wa nisalẹ lo jona gidi, pẹlu awọn dukia ti wọn o ti i le diwọn iye owo wọn. O ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii, awọn si ti n tọpasẹ awọn janduku naa lọ, o lo daju pe ko sẹnikan to lọwọ ninu ijamba yii ti ko ni i fimu kata ofin.

Bakan naa ni Ọgbẹni Ismail Adeleke to jẹ darẹkitọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ hulẹhulẹ ohun to ṣokunfa ina ojiji yii, awọn si maa jẹ karaye mọ okodoro otitọ nipa ẹ.

Leave a Reply