Awọn ọlọpaa ti tun mu Ṣoworẹ atawọn ẹgbẹ ẹ l’Abuja o

Faith Adebọla

Ọmọyele Ṣoworẹ, ondupo aarẹ ilẹ wa nigba kan, ati agbatẹru iwọde tako iṣejọba Aarẹ Buhari (Revolution Now)  ti wa lakata awọn agbofinro bayii, awọn ọlọpaa ni wọn mu un laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, l’Abuja.

Iroyin kan to tẹ wa lọwọ lati Abuja sọ pe awọn ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa, RRS, lo fi pampẹ ofin gbe ọkunrin naa atawọn ẹlẹgbẹ rẹ kan nibi ti wọn ti n ṣe ikọwọọrin ati iyide kiri awọn agbegbe kan l’Abuja lati sami si ibẹrẹ ọdun tuntun 2021 ta a mu loni-in.

Ikorita Gudu lẹnikan to ba Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa sọrọ, sọ pe wọn ti mu Ṣoworẹ ati diẹ ninu awọn ẹlẹgbẹ ẹ, ki wọn to fi mọto ọlọpaa gbe wọn lọ sibi tẹnikan o mọ.

Ṣaaju ni Ṣoworẹ ti kede lori atẹ ayelujara rẹ pe kawọn ọmọ Naijiria dara pọ mọ oun laaarọ ọjọ ọdun tuntun fun iyide tawọn fẹẹ ṣe, lati sami si ibẹrẹ ọdun 2021. O lawọn fẹẹ rin lọwọọwọ kaakiri awọn agbegbe pataki kan niluu Abuja ni.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ. Oṣerekunrin ilẹ Ghana …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: