Awọn ọlọpaa ti wọn lọọ pese aabo lasiko ibo Edo lasidẹnti lojiji, marun-un ku ninu wọn 

Adewale Adeoye

Marun-un lara awọn ọlọpaa ipinlẹ Kano, kan ti wọn lọọ pese aabo fawọn araalu lasiko eto idibo to waye nipinlẹ Edo, laipẹ yii ni wọn ti ku sinu ijamba ọkọ kan to waye lasiko ti wọn n pada lọ sibi ti wọn ti wa. Ijamba ọkọ ọhun waye lojuna marosẹ Zaria si Kano, nipinlẹ Kano, lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Ṣa o, awọn agbofinro mọkanla yooku ti wọn ko ku, ṣugbọn ti wọn fara pa yannayanna ninu ijamba naa wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun nileewosan Muritala Muhammad Specialist Hospital, to wa nipinlẹ Kano, nibi tawọn dokita ti n du ẹmi wọn.

Awọn ọlọpaa marun-un ọhun ni: Insipẹkitọ Hashimu Garba, Insipekitọ Usman Salisu, Sajẹnti Saidu Salisu, Kọburu Kamala Shehu, ati Kọburu Abubarkar Nuhu.

ALAROYE gbọ pe lati ipinlẹ Edo, nibi ti eto idibo sipo gomina ipinlẹ naa ti waye laipẹ yii lawọn ọlọpaa naa ti n bọ, bi wọn ṣe deluu kekere kan ti wọn n pe ni Karfi, nijọba ibilẹ Kura, nipinlẹ Kano, ni mọto ti wọn wa ninu rẹ lọọ fori sọ ọkọ mi-in to n bọ. Loju-ẹsẹ ni marun-un lara wọn ti ku.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Abdullah Haruna Kiyawa, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe ibi iṣẹ ilu lawọn agbofinro ọhun ti n bọ, ṣugbọn nigba to ku diẹ ki wọn dele lati ipinlẹ Edo ti wọn ti n bọ lọkọ wọn lasidẹnti lojiji, ti marun-un ninu wọn si ku loju-ẹsẹ, nigba tawọn mọkanla mi-in n gba itọju lọwọ nileewosn ijọba kan to wa lagbegbe naa.

Alukoro ni ọga agba ileesẹ ọlọpaa orileede yii ti ranṣẹ ibanikẹdun si awọn ẹbi oloogbe naa.

 

Leave a Reply