Awọn ọlọpaa yinbọn pa akẹkọọ poli kan nibi ti wọn ti n dawọọ idunnu l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Wahala mi-in tun ti waye nipinlẹ Ekiti bayii pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe yinbọn lu eeyan meji nileetura Queens Court Hotel, to wa loju ọna Ado-Ekiti si Ikẹrẹ-Ekiti, o si ṣe ni laaanu pe ọkan ninu wọn ti jẹ Ọlọrun nipe. Oloogbe naa la gbọ pe o jẹ ọmọleewe Poli kan, Ọlaoye Akintayọ si lorukọ ẹ.

ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye lasiko tawọn ọlọpaa naa sin igbakeji ọga-agba ọlọpaa kan lọ si otẹẹli ọhun, nibi ti wọn ti deede yinbọn lu awọn ọmọkunrin naa ki wọn too sare ko wọn lọ sileewosan, ti wọn si sa lọ kawọn eeyan too ri wọn.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ yii sọ fun wa pe awọn ọlọpaa bii marun-un lo tẹle ọga wọn yii lọ si otẹẹli naa, bẹẹ ni ki i ṣe pe nnkan kan ṣẹlẹ to di eto aabo lọwọ, awọn ọlọpaa ọhun kan n dunnu ni, wọn si da ibọn bolẹ. Lasiko naa ni ibọn ba Ọlaoye nikun, ọta naa si jade lẹyin ẹ, ẹsẹ lo si ti ba ọkunrin keji ti a ko ti i mọ orukọ ẹ.

Bi awọn ọlọpaa ọhun ṣe ri i pe awọn ti daran ni wọn sare gbe awọn ọkunrin meji naa lọ si ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti (EKSUTH), ṣugbọn ki wọn too debẹ ni Ọlaoye ti ku, nigba ti ekeji wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun. Bi awọn agbofinro ọhun ṣe gbe wọn silẹ tan ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ, wọn si fi ọkọ Ford to ni nọmba PF 600 WSH ti wọn gbe wa silẹ.

Nigba to di aarọ ọjọ keji tawọn araalu gbọ iroyin naa ni wọn ya bo ileewosan ọhun lati wo ọkọ naa, ninu ẹ ni wọn si ti ba kaadi idanimọ ọlọpaa kan ati fọọmu owo ifẹyinti ọlọpaa ọhun, ẹni to n jẹ Sajẹnti Tizhe Goji.

Lẹyin wakati diẹ tawọn eeyan ti n wo mọto naa lawọn kan tinu n bi yọ awọn taya mọto ọhun, bẹẹ lawọn mọlẹbi oloogbe naa fara ya, wọn si tun lọ si aafin Ewi tilu Ado, Ọba Rufus Adejugbe, nibi ti wọn ti beere fun idajọ ododo.

Bakan naa la gbọ pe wọn ti gbe oku Ọlaoye lọ si mọṣuari ileewosan aladaani kan, bẹẹ ni wọn gbe ẹni tibọn ba lẹsẹ lọ si ileewosan igbalode Afẹ Babalọla to wa l’Ado-Ekiti.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe ọwọ ti tẹ ọlọpaa tawọn gbọ pe o yinbọn lu awọn eeyan naa, o si ti wa ni olu-ileeṣẹ wọn to wa loju ọna Iyin-Ekiti.

Abutu ni, ‘‘A fidi ẹ mulẹ pe wọn yinbọn ni ọtẹẹli kan l’Ado-Ekiti, awọn meji nibọn si ba, ninu eyi ti ọkan ti dagbere faye. Ọlọpaa ti wọn tọka si pe oun lo yinbọn wa lọdọ wa lọwọlọwọ, CP Tunde Mobayọ to si jẹ Kọmiṣanna ọlọpaa ti sọ pe iwadii ijinlẹ gbọdọ waye lori iṣẹlẹ naa.

‘‘ Ko si nnkan ta a maa fi pamọ ninu iṣẹlẹ yii. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa yii ki i ṣe ti Ekiti, ọdọ wa ni wọn ti ṣaṣemaṣe, wọn yoo si jiya tiwadii ba fi han pe wọn jẹbi.’’

Leave a Reply