Awọn ọlọpaa yinbọn pa Baba Ifa niluu Ajaawa, wọn tun gbe iyawo ati dẹrẹba rẹ lọ

Faith Adebọla

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ara ko ti i rọ okun, bẹẹ ni ko ti i rọ adiẹ niluu Ajaawa, nijọba ibilẹ Ogo-Oluwa, nitosi Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ.

ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn ọlọpaa ya wọ ilu naa lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọ lakọ. Asiko ti wọn n yinbọn yii ni wọn yinbọn pa Olori awọn onifa niluu naa, Ifalẹyẹ Jayeọla, beẹ nibọn wọn tun pa ẹni kan, ti ọpọ eeyan si fara pa yannayanna.

Awọn araalu naa ko tete mọ pe ọlọpaa ni wọn pẹlu bi wọn ṣe dabọn bolẹ, ajinigbe ni wọn pe wọn. Mọto Siena mẹta la gbọ pe wọn gbe wọ abule naa, bi wọn si ti debẹ ni wọn n yinbọn ni nnkan bii aago kan oru.

Alaga ijọba ibilẹ Ogo-Oluwa, niluu Ajaawa, Ọgbẹni Ṣeun Ojo, ṣalaye fawọn oniroyin niluu Ibadan pe awọn eeyan ni wọn pe oun nipe ijaya pe awọn ọlọpaa ti ya wọnu ilu naa, ti wọn si n yinbọn lakọlakọ. O ni awọn ko kọkọ gbagbọ pe awọn ọlọpaa lo wọ abule naa ti wọn n yinbọn, afigba ti awọn de Area Commander, tawọn si lọ sọdọ DPO, ẹni to fidi rẹ mulẹ pe awọn agbofinro naa forukọ silẹ nibẹ ki wọn too wọ ilu Ajaawa wa lati waa ṣiṣẹ buruku naa.

Ojo ni, ‘A fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa tootọ ni awọn eeyan naa, wọn si ni latọdọ ọga ọlọpaa patapata niluu Abuja ni wọn ti wa. Ṣugbọn o jẹ ohun to ya ni lẹnu pe awọn ọlọpaa le deede wọnu ilu bẹẹ, ki wọn si maa yinbọn ti wọn fi da wahala silẹ to fi di pe gbogbo ilu n sa kijokijo kiri.’’

Alaga yii ni eyi lo mu ki oun waa fi ọrọ yii lọ lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ibadan. O fi kun un pe eeyan meji lo ti padanu ẹmi wọn, nigba ti awọn bii mẹwaa fara pa.

Leave a Reply