Awọn ọlọpaa yinbọn pa ẹni kan n’Ire-Ekiti nitori ọdun Ogun

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Walaha nla ti bẹ silẹ niluu Ire-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti, kori bi kabiyesi ilu naa, Ọba Victor Adeleke Bọbade, ṣe kede pe ọdun Ogun tọdun yii ko ni i waye nitori konilegbele ti arun Korona da silẹ.

Lanaa, ọjọ Aiku, Sannde, la gbọ pe awọn ọdọ ti inu wọn ko dun si ikede naa kọlu aafin, ori lo si ko kabiyesi yọ ko too raaye kuro lagbegbe naa.

Lọwọlọwọ bayii, a gbọ pe awọn ọlọpaa ti yinbọn pa ẹnikan ninu awọn to n fi ẹhonu han, ati pe nnkan ti daru patapata niluu naa.

Leave a Reply